You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sanwo-Olu tún la Gbadebo Rhodes-Vivour àti Adediran ‘Jandor’ mọ́lẹ̀ nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to fi ikalẹ si ilu Eko ti fi ontẹ lu Babajide Sanwo-Olu gẹgẹbii gomina ti awọn eeyan ipinlẹ Eko dibo yan nitootọ.
Gbadebọ Rhodes-Vivour to jẹ oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu LP ati Abdulazeez Ọlajide Adediran to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP pẹ ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ to gbọ awuyewuye esi ibo gomina ni ipinlẹ Eko to ni ẹjọ wọn ko lẹsẹ nlẹ lati tako Sanwo-Olu gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko.
Ninu idajọ ti awọn adajọ to joko gbọ ẹjọ naa fẹnuko le lori, wọn ni ipẹjọ kotẹmilọrun ti Gbadebọ ati Adediran pe ko lẹsẹ nlẹ ati wi pe Inec ko jayopa lori kikede Babajide Sanwo-Olu gẹgẹbi gomina ti awọn eeyan ilu Eko dibo yan ati bafẹmi Hamzat gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Onidajọ Yargata Nimpa, Samuel Bọla ati Onidajọ Paul Bassey lo gbe idajọ naa kalẹ.
Bawo lọrọ ṣe bẹrẹ?
Gomina Sanwo-Olu jawe olubori ninu ibo gomina to waye nipinlẹ Eko lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023 pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹrin ati meji o le mẹrinlelaadoje (762,134).
Gbadebọ Rhodes-Vivour ti ẹgbẹ oṣelu LP lo ṣe ipo keji pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna ọdunrun ati mejila o leọdunrin ati mọkandinlọgbọn (312,329).
Abdulazeez Adediran to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo yii kan naa ni ibo ẹgbẹrun mejilelọgọta o le irinwo ati mọkandinlaadọta (62,449).
Esi ibo naa ko dun mọ awọn oludije ẹgbẹ oṣelu LP ati PDP ninu ni wọn ṣe gba ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo gomina ni ipinlẹ Eko lọ.
Ile ẹjọ naa gbe idajọ kalẹ ni ọjọ karundinlọgbn oṣu kẹsan an ọdun 2023 pe ẹjọ ti awọn mejeeji n pe ko lẹsẹ n lẹ bi o ti wulẹ ko mọ.