Ibadan clash: Èèyàn bí méjì kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò tí àwọn afurasí ọmọ Auxiliary àti Isota kọlu ara wọn ní Ibadan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan meji ti iroyin sọ pe o ku, ti ọpọ si farapa lasiko ti awọn afurasi ti wọn lo jẹ ọmọ igbimọ alamojuto awọn gareeji ọkọ, PMS, nipinlẹ Oyo, kọlu awọn janduku.

Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ni iroyin sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni opopona Ali-Iwo si Oje, nilu Ibadan.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe fun ọpọlọpọ iṣẹju ni awọn ara adugbo naa, ati awọn to n kọja lọ fi n sa asala fun ẹmi wọn nitori iro ibọn to n dun.

"Yatọ si ibọn, oriṣiriṣi nkan oloro ni awọn igun mejeeji fi kọju ija sira wọn."

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ koko nkan to fa ija igboro naa, ileeṣẹ iroyin abẹle, Oyo Insight, sọ pe alaga igbimọ PMS, Mukaila Lamidi Auxiliary lo lọ si ibuba awọn janduku Were.

Awọn miran sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ janduku, Isota Boys, lo bẹrẹ wahala ni kete ti wọn fi oju ri awọn ọmọ Auxiliary to wọ aṣọ to ni aworan rẹ ati ti Gomina Seyi Makinde lara.

Bakan naa ni awọn janduku naa ba awọn ọkọ jẹ.

Ija naa waye fun ọpọlopọ iṣju, ki awọn ọlpaa to o de lati da alaafia pada si agbegbe naa.

Igbiyanju wa lati ba agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Adewale Osifeso, sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ja si pabo, nitori pe ko gbe ipe rẹ lori foonu.

Ohun to yẹ ki o mó nipa igbimọ Park Management Service, PMS

Ọdun 2019 ni Gomina Seyi Makinde gbe igbimọ oluṣakoso naa kalẹ, lati ma ṣamojuto awọn ibudokọ nipinlẹ Oyo, dipo ẹgbẹ NURTW to n mojuto wọn tẹlẹ.

Gomina Makinde sọ pe ọna lati dena wahala ni ẹka igboke-gbodo ọkọ, lo mu ki oun ṣe ayipada ẹgbẹ NURTW.

Fun'ra awọn ọmọ ẹgbẹ naa si lo ma n yan awọn adari wọn amọ Gomina Makinde fi ofin de ẹgbẹ NURTW naa nitori rogbodiyan to n waye ni gbogbo igba nipa yiyan awọn adari rẹ.

Ijọba Oyo sọ pe PMS ko ni ibaṣepọ pẹlu NURTW. Ijọba lo gba awọn ọmọ ikọ PMS si iṣẹ lati di gbogbo ibi ti owo n gba poora, ki wọn si tun ri i daju pe owo to n wọle fun ijọba pọ si.

Wọn tun gbọdọ ri daju pe owo to tọ si ijọba n de apo rẹ, ojuṣe ikọ PMS si tun ni lati ri pe kosi sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ, nipa ṣiṣe amojuto awọn ibudokọ.

Ṣugbọn ṣa, idasilẹ igbimọ PMS ko da ija igboro duro laarin awọn awakọ. O ti to bi igba meji si mta ti awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW akọkọ ati awọn alatilẹyin Auxilairy kọju ija si ara wọn.