Isreal first flight to UAE: Ìjà d'ópin, fún ìgbà àkọ́kọ́, bàálù gbéra láti Israel lọ sí UAE

Eyi jẹ imupada bọ sipo ibasepọ orilẹ-ede mejeeji, lẹyin ti wọn kede pe awọn ti sinmi ogun.

Baalu Israel El Al ni yoo rin irinajo o ni wakati mẹta ọhun, lati gbe awọn aṣoju orilẹ-ede Israel ati US.

Wọn fi aaye gba baalu naa lati gba oju ofurufu orilẹ-ede Saudi Arabia kọja, eyi ti kii ribẹ tẹlẹ.

Wọn maa n ti i mọ àwọn baalu to ba n bọ lati Israel ni tẹlẹ.

Orilẹ-ede UAE ni ìkẹta nilẹ Arab, to mọ si itẹwọ gba Israel gẹgẹ bi i orilẹ-ede, lati ọdun 1948 to ti wa.

Ọjọ Satide ni UAE pa ofin to ṣe lọdun 1972, lati ma ni ibasepọ pẹlu Israel, rẹ.

Ibẹrẹ oṣu yii si ni orilẹ-ede mejeeji ṣi oju opo ẹ̀rọ ibanisọrọ silẹ (láti ma a gba ipe laarin ara wọn) fun igba akọkọ.

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ni wọn kede pe ija ti tán, lẹyin ti ilẹ America ba wọn laja.

Ṣaaju orilẹ-ede UAE, Egypt àti Jordan nikan lo da Israel mọ gẹgẹ bi orilẹ-ede, laarin awọn orilẹ-ede ilẹ Arab, ni Middle East.

Awọn onwoye l'agbaye sọ pe eyi yoo tubọ mu ki alaafia jọba ni Middle East.