Huawei: Àwọn ohun márun un ti o n ja ilẹ Amẹrika laya nipa ile iṣẹ China yi

Oríṣun àwòrán, AFP
Loni ni ile iṣẹ to n pese ẹrọ ibanisọrọ alagbeka Huawei yoo ṣe afihan awọn ẹrọ alagbeka rẹ tuntun ti o si ti fiwe pe awọn akọroyin lati wa foju ba ayẹyẹ naa.
Amọ awọn ẹrọ naa ko ni ka oju osunwọn ti a mọ wọn si tẹlẹ nitori bi ile iṣẹ Google ti ṣe gbegidina mimu ayipada ba awọn aapu kọọkan lori ẹrọ alagbeka Huawei.
Igbesẹ Google yi ko ṣẹyin ikede aarẹ Amerika Donald Trump pe ohun fẹ da aabo bo ẹrọ alatagba kọmputa orileede naa lọwọ awọn aṣebi lati ilẹ okere.
Awọn onwoye ni ile iṣẹ orileede China yi ni ikede na doju le.
Toun ti pe ẹrọ alagbeka ni awọn eeyan mọ Huawei fun,wọn a tun ma pese awọn irinṣẹ fawọn to n ṣeto ibanisọrọ.
Ki gaan lo n mu Amẹrika jaya nipa Huawei?
Ẹsun orisirisi ni wọn ti fi kan ile iṣẹ Huawei pe o lọwọ ninu titọ pinpin awọn ile iṣẹ ẹrọ amuṣẹya ati pe o n lẹdi apo pọ pẹlu Iran.
Ninu ọrọ ti Huawei gbe jade, o ni awọn ko ni dawọ pipese ''security updates'' ati awọn iṣẹ miran fawọn alabara awọn lori ọja tawọn fẹ ta,tabi ti wọn ti ta tẹlẹ kaakiri agbaye.
Wọn ni awọn yoo pese ọna abo lati ma fi lo ẹrọ ilewọ tabi kọmputa eleyi ti yoo ṣe anfaani fawujọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5G: O yara bi aṣa ṣugbọn ṣe kii ṣe wi pe o lewu?
Huawei ti bẹrẹ si ni jiroro pẹlu awọn orileede kan pe ohun fẹ sagbatẹru lilo ẹrọ alagbeka lori ayelujara ayarabiasa to n lo 5G.
Lilo aiyelujara 5G yi yoo yara gaan lawọn ibi ti wọn ba ti n lo wọn.Lawọn orileede mii,wọn le fi wọn dari ọkọ lalai ni ẹni to n wa.
Bi Huawei ba fi le sagbatẹru imọ 5G yi,awọn akẹgbẹ orileede China ni anfaani re e fun China lati ma tọpinpin gbogbo atẹjiṣẹ awọn eeyan lori ẹrọ alatagba.
Koda wọn le lo lati fi dina mọ ẹrọ alatagba tawọn ti eleyi ṣi le da wahala silẹ.
Saaju ki Donald Trump to buwọlu aṣẹ yi, orileede US ti lewaju awọn to n fin ina mọ awọn orileede miran lati yago fun ile iṣẹ Huawei.
Gbogbo lalakokofẹfẹ 5G yi ko sẹyin pe awọn orileede marun un kan ti wọn ko ara wọn jọ lati ma tọ pinpin awọn orileede miran,''Five-Eyes'' latara iroyin gbigba lori ayelujara
Lara awọn orileede to ti gba lati lo 5G Huawei yi la ti ri UK,Canada,Australia ati New Zealand .

Oríṣun àwòrán, PA
Amẹrika ti tutọ soke foju gba pe eyikeyi ninu awọn orileede Five-Eye to ba tẹwọgba 5G Huawei,awọn ko ni ba ni ajọṣepo mọ.
Akọwe agba Amẹrika Mike Pompeo ni ''bi orileede kankan ba gba 5G to si fi si ẹrọ alatagba wọn,a ko ni ba wọn aṣepọ mọ.''
Lọpọ igba ni Huawei ti ni awọn kii ṣe iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ titọpinpin forileede China amọ awọn ti o mọ nipa iru nkan bayi ni yoo ṣoro ki ile kankan to le kọ lati ma ṣiṣẹ titọpinpin fun ijọba China.

Awuyewuye robot arm
Bi ko ba daju pe Huawei mọ nipa awọn ẹsun miran,eleyi ti ko ruju rara ni ti eleyi ti wọn fi kan awọn onimọ ẹrọ rẹ kan ti wọn ni wọn ji ''robot arm.''
Oṣiṣẹ Huawei naa irinṣẹ naa ti wọn ma fi n sayẹwo oju gilasi ẹrọ alagbeka ṣeṣi jabọ sinu baagi agbekọpa oun bi ohun ti ṣe n kuro nibi ile isẹ T-Mobile kan.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ile isẹ orileede Germany kan ti wọn jijọ n ṣiṣẹ pẹlu Huawei lawọn ko gba ọrọ yi gbọ.Wọn pada pari ọrọ naa ni tunbi n nubi ni.
Awuyewuye tun pada ruwe nigba ti o han gbangban pe onimọ ẹrọ Huawei mii lọwọ ninu mimu robot arm yi ati pe awọn ọga rẹ lati China ni wọn ran niṣẹ naa.
Bi ẹko ba ranti,eyi wa lara awọn idi ti wọn fi mu ọga ọrọ owo Huawei Meng Wanzhou ni Canada lọdun to kọja.
Lilẹ idi apo pọ pẹlu Iran?
Yatọ si wahala to de ba ọga Huawei yi pe ki wọn ma lọ ṣẹjọ rẹ l'Amẹrika,arabirin Meng n koju awọn ẹsun miran to fi mọ pe ile iṣẹ Huawei lẹdiapopọ pẹlu Iran.
Ohun ta gbọ ni pe o mọ nipa bi Tehran ṣe mori bọ ninu ijiya Amẹrika nipa ile iṣẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Skycom.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan ni pe o parọ fawọn ile iṣẹ ifowopamọ ati orileede Amẹrika nipa ibaṣepọ pẹlu Iran.
Arabinrin Meng - to jẹ ọmọ oludasilẹ Huawei- ni oun ko jẹbi ẹsun naa. O ṣeṣe ki wọn dajọ ẹwọn ọgbọn ọdun fun ti wọn ba gbẹjọ rẹ l'Amẹrika.
Amọ ṣa idaamu Huawei l'Amẹrika ko pin sibẹ.
Gẹgẹ bi ohun ti Bloomberg sọ,ile iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI n ṣe iwaadi ile iṣẹ naa tori pe o tapa sofin to ni ṣe pẹlu kiko nnkan ija,International Traffic in Arms Regulations (ITAR) nitori bi o ti ṣe n lo gilasi rẹ ti nkankan ko le fọ.
Ti o ba ti lo ẹrọ alagbeka ri ti oju rẹ si fọ, o mọ bi ko ti ṣe nira ki oju rẹ fọ ṣugbọn wa mọ inira to wa nibi nina owo pupọ lori piparọ rẹ.
Awọn ẹrọ alagbeka to ni oju gilasi ti kii fọ jẹ nnkan nla lagbo imọ tẹkinọlọgi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile iṣẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Akhan Semiconductor dunadura pẹlu Huawei nipa bi wọn yoo ti ṣe lo gilasi oju foonu wọn to lagabara daada.
Gẹgẹ bi ohun ti Bloomberg sọ, ko pẹ ti wọn fi da awọn iru gilasi ti wọn kọkọ fi sọwọ si wọn pada pe niṣe ni wọn n fọ.
Ọrọ ko tan sibẹ́
Pẹlu gbogbo wahala wọn yi,igbesẹ Google yi pẹlu aṣẹ ti aarẹ Trump pa,Huawei kii ṣe ile iṣẹ ti a fi ọwọ rọ sẹyin lagbaye.
Bi a ba ṣafiwe paapa julọ lawọn orileede to wa ni Afrika ati Asia iye ti Huawei n ta ọja wọn si ti eyi to n wa lati Amerika tabi Yuroopu,iku ko ṣe fi we oorun lọrọ awọn mejeeji.
Lọja agbaye, Huawei yoo ṣi ma jẹ aayo ọpọ nitori iye ti o n ta ọja tirẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Koda nilu ọba to jẹ kan lara awọn alabaṣepọ Amẹrika timọtimọ wọn ṣi n jiroro lori boya ki wọn lo irinṣẹ Huawei lati ṣe itakun 5G tiwọn.
Laipẹ yi ni awọn kan bnu atẹ lu minisita ọrọ abo Britain tori pe o fẹ lo awọn irinṣẹ Huawei kan faabo wọn.
Wọn ṣi n jiroro nipa rẹ,omi gbona fẹ suru lọrọ to wa nilẹ yi agaga to ba ti ni ohun ṣe pẹlu Huawei.
Ko si ẹni to le sọ ibi ti ọrọ yoo fi si lọjọ iwaju.















