Network of Niger Delta Republic Fighters: Àwọn ajìjàgbara Niger Delta fẹ́ yapa kúrò ní Nàíjíríà

Ẹgbẹ ajijagbara kan ti wọn pe ara wọn ni 'Network of Niger Delta Republic Fighters' ti dun'koko pe wọn yoo yapa kuro lara orilẹede Naijiria, ti wọn yoo si daduro ni ọjọ kini, oṣu kẹfa ọdun yii.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Aje, wọn wipe inu awọn ko dun si bi nkan ṣe ri ni Naijiria.
Alukoro ẹgbẹ naa, Maxwell Dan ninu atẹjade naa wi pe ijọba aarẹ Buhari fi iwa ẹlẹyamẹya ba wọn lo.
Lara iwa ẹlẹyamẹya to ka ni bi awọn ọlọọpa ṣe ya wọ ile okan lara awọn agba ilẹ Niger Delta, oloye Edwin Clark, ati iponju ti adajo agba Naijiria tẹlẹri, adajọ Walter Onnoghen n la kọja. O tun wipe ijọba aarẹ Buhari yọ ọmọ ọgbẹni Mathew Seiyeifa to jẹ ọmọ Niger Delta kuro ni ipo ọga ile iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lọna ti ko tọ.
Siwaju si, ẹgbẹ naa wipe fun ọdun mẹrin ti aarẹ Buhari fi wa lori aleefa, ko si ipa idagbasoke kakan ni agbegbe Niger Delta.
Awọn di wonyi jẹ lara idi ti ẹgbẹ naa fi pe fun iyapa kuro lara orilẹede Naijiria.










