Brexit: Theresa May yóò ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olórí EU láti dóòlà ìpinnu rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olootu ijọba orilẹede United Kingdom, Theresa May yoo ṣapade pẹlu awọn olórí àjọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, EU ni Ọjọ Iṣẹgun fun ijiroro lati doola igbesẹ ti yoo yọ orilẹede Britain kuro ninu ajọ naa.
May yoo jiroro pẹlu Olootu ijọba orilẹede Netherlands, Mark Rutte ati ti Germany, Angela Merkel, lẹyin to ti sun ọjọ toyẹ ki ile aṣofin kekere ni orilẹede UK o dibo lori bi Britain ṣe fẹ ẹ kuro ninu ajọ EU siwaju.
Aarẹ ajọ EU, Jean-Claude Juncker sọ pe ajọ EU ko ni 'pada duna-dura'' lori igbesẹ ti Britain fẹ ẹ gbe ọhun, ṣugbọn anfaani wa fun 'ṣiṣe alaye lẹkunrẹrẹ.''
O f'ojuhan pe May n wa idaniloju ofin pe orilẹede UK ko ni forisanpọn ninu igbesẹ lati mu ki ohun ati orilẹede Northern Ireland maa lo adehun to faaye gba pe ko ni i si owo ori sisan lori ọja tabi ẹru to ba n wọ orilẹede kan lati ikeji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn kan to bẹnu ẹtẹ lu igbesẹ naa woye pe orilẹede United Kingdom ko le yọ ọwọ kuro ninu adehun lilo ofin kan na fun ẹnu'bode ilu pẹlu Northern Ireland laiṣe pe ajọ EU f'ọwọ si.









