Marathon Sex Poly Student: Irọ́ ni ìròyìn pé ìbálòpọ̀ "11 rounds" ni Oromidayo David àti olólùfẹ́ rẹ̀ ní tó pa wọ́n

Ni gbara ti akọroyin BBC Yoruba de agbegbe ibi ti iṣlẹ iku ọmọ ile ẹkọ gbogboniṣe ti Ibadan ati ololufẹ rẹ ti waye, ọrọ yatọ gedegbe si ohun tawọn eeyan n ri lori ayelujara.

Ọpọlọpọ wọn ni ko fẹ fi oju han ayafi ọkunrin kan to ni oun rinrinajo amọ oun ṣẹṣẹ de laipẹ yii ni.

Awọn araale sọ fun BBC Yoruba pe awọn ko le fi aridaju han pe ibalopọ to gbona giiri lo pa wọn.

Ọrọmidayọ David ati Adeleke Aramide ni orukọ awọn ololufẹ mejeji ọhun.

Ki lo ṣẹlẹ gangan?

"Inu ile ni won gbe ẹrọ amunawa Generator yẹn si, wọn ṣṣẹ ra a ni amọ ita ni wọn saba maa n gbe e si, a o mọ idi ti wọn fi gbe e sinu ile lọjọ yẹn".

Ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbe sọ pe boya won kan ro o wipe ọjọ ti lọ ni pe ki wọn ma gbe ẹrọ amunawa ọhun sita mọ.

Ni ti awọn to ni pe wọn lo oogun oloro, awọn ara adugbo sọ pe irọ ni wọn npa, "Ko si ọrọ to fidi rẹ mulẹ pe ibalopọ tabi ogun lo fa iku won".

Awọn ara adugbo rẹ fi aridaju han pe kii lo ogun fun iwosan gan ka tọ sọ oogun oloro tori wọn maa n gbọ ti ọrẹbinrin rẹ ti wọn jọ wa gba ile ti wọn si jọ n gbe maa n rọ ọ lati lo ogun bo ba ṣaarẹ.

Eyi lo fi aridaju han pe ọrẹbinrin rẹ gan kọ ni ẹni ti wọn jọ ku yii bi ko ṣe obinrin kan ti wọn kan jọ pade.

Wọn ṣalaye pe ọrẹbinrin rẹ gangan ti wọn jọ n gbe igbe aye lọkọlaya ti rinrinajo.

"Wọn ṣe eto kan to n jẹ "Back to school" nibi ti gbogbo awọn to n kẹkọ jade ti n ṣe ajọyọ".

O ni awọn to mọ wọn ni oun ati arabinrin yẹn ṣẹ pade nibẹ ni torinaa ko tii pe ọsẹ kan rara ti wọn mọ ara wọn ti arabinrin yẹn ṣe wa a wa sile.

Amọ BBC Yoruba ko le fidi gbogbo ọrọ yii mulẹ. Ohun ti Ọlọpaa sọ fun wa ni pe lootọ ni iku wọn waye, iwadi si ti n lọ lọwọ.

"Bí a ṣe ba Oromidayo ati ololufẹ rẹ ninu ile iyagbẹ"

Awọn araale ṣalaye pe inu ile igbọnsẹ lawọn ti ba oku awọn mejeji to si jẹ pe ihoho ọmọluabi ni wọn ba awọn mejeeji.

"Igbẹ jade nidi wọn, a ri igbẹ lara awọn mejeeji, obinrin yẹ ka to si fi ẹyin lọ silẹ amọ ọkunrin yẹn na silẹ gbalaja ni"

Wọn ni iwe ti wọn n ka wa lori koto iyagbẹ eyi ti wọn fi han BBC pẹlu alaye pe wọn ni awọn ni idanwo ti wọn si n kawe fun lọwọ.

Awọn ara adugbo ni irọ patapata ni awọn to ni ẹrọ to n da omi wa ninu ile iyagbẹ naa.

Arakunrin kan ni "wọn ba wọn ninu ile iyagbẹ ni.

Iya agbalagba ti a ba sọrọ ti ko fẹ foju han sọ pe wn ṣi ba eemi lara arabinrin yẹn amọ kunrin ti gan pa.

Wọn ni bi igba ti ilẹ ba yọ eeyan ni.

"Bi ko ba soju ẹnikẹni, wọn ko le sọ ohun ti wọn ko ri amọ o fihan pe wọn ko si pẹlu ipo ọkan to dara ti wọn fi ku.

"O dẹ mu obinrin yẹn dani gbagba titi doju iku ni".

Amọ o ni gbogbo awọn lawọn mọ pe o ṣeeṣe ko jẹ eefin ẹrọ amunawa ti wọn gbe sinu ile nibi faranda yara wọn lo fun wọn lọrun to si fa idiwọ fun eemi.

Ko tii si ohunkohun to fihan pe wọn ba ara wọn lo fun wakati pipẹ tabi wọn lo oogun oloro.

Ki ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ sọ?

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ gbogboniṣe Poly Ibadan ti tan imọlẹ si iṣẹlẹ iku akẹkọọ wọn kan ti iroyin gbode pe o dero ọrun lẹyin ibalaopọ oniwakati pipẹ.

Gẹgẹ bi ile ẹkọ naa ṣe sọ fun akọroyin BBC, lootọ ni akẹkọọ naa ku ati pe akẹkọọ ilẹ ẹkọ naa nii ṣe.

Alukoro Poly naa, Soladoye Adewole jẹri pe akẹkọọ ipele ẹkọ giga NDII ni arakunrin Oromidayo Daniel ṣugbọn ko sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ.

O ni o jẹ ẹdun ọkan fun fasiti naa pe wọn padanu Daniel to yẹ ko kọ idanwo aṣekagba NDII.

Ninu apejuwẹ rẹ, o ni Daniel jẹ akẹkọọ to gbajumọ ẹkọ rẹ ati pe oun ni akẹkọọ to pegede julọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

O gba ladura pe ki eledua rọ awọn mọlẹbi rẹ loju lori ipapoda akẹkọọ yi.

Ṣe ibalopọ oniwakati pipẹ lo ṣokunfa iku Daniel?

Ibeere yi ti o gba ọkan gbogbo eeyan to gbọ nipa iṣẹlẹ yi ni BBC fi nawọ si alukoro Poly Ibadan.

Ninu esi rẹ, o ni ''ṣe ẹnikankan wa nibẹ lati le fidi rẹ mulẹ pe wọn ni ibalopọ wakati pipẹ ni?''

O ni tori eleyi ko yẹ ki eeyan maa sọ ọrọ ti yoo fi daran ofin.

''Ibalopọ oniwakati pipẹ tawọn eeyan n sọ, ta lo wa nibẹ?Bi eeyan ba lu magun, ṣe ibalopọ iṣẹju marun un ko le mu sọda sọrun ni?''

Adewole sọ pe ni ita ọgba ile ẹkọ naa ni akẹkọọ naa n gbe tori naa awọn ko le sọ pato iru iku to pa ṣugbọn awọn agbofinro yoo tan imọlẹ si.

Ki lawọn ọlọpaa sọ

BBC Yoruba tẹsiwaju lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo Adewale Osifeso ko tan imọlẹ si iṣẹlẹ yi.

Osifẹsọ naa sọ pe lootọ lawọn gbọ nipa iṣẹlẹ yi amọ ẹkunrẹrẹ alaye lori bo ti ṣe ṣẹlẹ ko ti de si eti igbọ oun.

Lara iroyin to gbode ti BBC fi tori rẹ fẹ ṣe iwadii ohun to ṣokunfa iku Daniel ni pe awọn eeyan ni ibalopọ oniwakati lo ni pẹlu ọrẹbinrin rẹ.

Latara rẹ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, Daniel dero ọrun.

Kudiẹkudiẹ to wa ninu iroyin yi pọ nitori ko si ẹni to ṣoju rẹ to le jẹri si pe iye igba bayi ni wọn fi ni ibalopọ.

Awọn onwoye si n sọ pe orisi nkan lo le fa iku rẹ ṣugbọn iwadii ẹkunrẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iku iyẹn autopsy lo le mu ki ọrọ yi ye gbogbo eeyan.