Oluwo: Aláàfin ni Ọlọ́run lò láti gbé òpó àwọn ọba Yorùbá ró

Oluwo ti ìlú Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti ṣe àbẹ̀wò baba kẹ́ẹ pẹ́ sí Aláàfin ìlú Oyo, Oba Lamidi Adeyemi Kẹta.

Oluwo tó kọ́wọ̀ rìn pẹ̀lú àwọn olóyè rẹ̀ ní àbẹ̀wò náà wà láti fikùnlukùn àti láti bù mu nínú omi ìmọ̀ Aláàfin, ẹni tó júwe bí bàbá tó ṣe fẹ̀yìntì.

Ó ní àmù ìmọ̀ Aláàfin tó máa ń fi gbogbo ìgbà kún ló máa ń fà á tí àwọn ènìyàn fi máa ń fẹ́ láti rìn súnmọ́ Aláàfin nígbà gbogbo.

"Bàbá tó ṣé pé ní bàbá ni Aláàfin, ó ṣe gbáralé àti láti fọkàntán. A ní àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán, wọ́n fẹ́ràn mi, èmi náà sì fẹ́ràn wọn pẹ̀lú."

"Mo wá láti wá fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Aláàfin gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi. Oríṣiríṣí èrò la jọ jíròrò lé lórí a sì ṣe àwàdà, Ó wù mí kí n rí wọn pẹ́ dáadáa."

Aláàfin ní Ọlọ́run lò láti fi gbé òpó ilẹ̀ Yorùbá dúró

Oluwo salaye siwaju si pe Aláàfin ni Ọlọ́run ń lò láti fi gbé òpó àwọn orí adé àti ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ dúró ní ilẹ̀ Yorùbá.

Oluwo tẹ̀síwájí wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni òun fẹ́ràn lára Aláàfin gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn tó máa ń dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló wí pé òun yóò máa tẹ̀síwájú láti túbọ̀ máa ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin nítorí àǹfàní pọ̀ tí òun yóò jẹ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí gígùn ta Aláàfin lọ́rẹ.

Lára àwọn tó bá Oluwo kọ́wọ̀ rìn ni Otunba ìlú Iwo, Olóyè Sikiru Wahab Atanda, Àrẹ̀mọ̀ ìlú Iwo, ọmọọba Adelani Akanbi, Moluberin ìlú Iwo, Mojirin ìlú Iwo, Olóyè Aro ìlú Iwo, Mosalu ìlú Iwo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.