You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS: Oluwo ṣàlàyé ọ̀nà tí ìwọ́de #EndSARS míràn yóò fi kẹ́sẹ járí
Fun ẹyin ti ẹ ba ro pe iran ti tan lẹyin iwọde #ENDSARS to mi orilẹede Naijiria tititi laipẹ yii, a dara ki ẹ tun ero yi ro daadaa.
Nibayii, Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti ke sawọn ọdọ ni ipinlẹ Ọṣun pe nigbakugba ti o ba tun ya lati ṣe iwọde miran tako iwa aitọ lorilẹede Naijiria, oun gan an ni ki wọn wa pe lati lewaju iwọde naa o.
Ẹyin naa kọ haa?
Bẹẹni Kabiyesi ṣe sọ ọ lasiko to n sọrọ nibi aperọ atunbọtan iwọde #EndSARS to waye ni ilu Oṣogbo.
Ijọba ipinlẹ Ọṣun gbe apero naa kalẹ lati jiroro loro awọn ọgbọn ati aṣiṣe to waye lasiko iwọde naa pẹlu ọna ati mu idagbasoke jade fun itẹsiwaju ipinlẹ naa.
Kabiyesi Oluwo, ba Akanbi ni oun ṣetan lati lewaju awọn ọdọ ninu iwọde yoowu ti wọn ba fẹ ṣe lati rii daju pe ẹhonu wọn de ọdọ awọn alaṣẹ gbogbo to ba yẹ.
O ni lara awọn aṣiṣe to farahan lasiko iwọde #EndSARS to waye naa ni aisi awọn eeyan kan ni pato ti wọn lee tọka si gẹgẹ bi olori tabi aṣiwaju.
O ni eyi lo ṣokunfa bi o ṣe rọrun fawọn janduku lati ja iwọde naa gba mọ wọn lọwọ ti wọn si lo anfani naa lati fi fọ ile ati dukia araalu gbogbo.
O ni ọna kan gboogi lati ṣe iwọde ti yoo kẹsẹjari ni lati ni awọn aṣiwaju to ṣee tọka si fun ijiroro pẹlu ijọba.