You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Amotekun Oyo: Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu fún Àmọ̀tẹ́kùn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀méjì gbáko
Gomina ipinlẹ Ọyọ Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣiṣọ loju ikọ Amọtẹkun ẹka ti ipinlẹ Ọyọ nibi ayẹyẹ kan to waye nilu Ọyọ l'Ọjọru.
Ninu ọrọ ti o sọ nibi ipejọpọ naa, Makinde ni lati igba ti wọn ti ṣe ifilọlẹ ikọ naa ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti n sa ipa rẹ lati jẹ ki Amọtekun bo si oju iṣẹ.
- Ṣeun Kuti fi òyìnbó àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá ṣe yẹ́yẹ́ tí wọ́n kọ tako ẹgbẹ́ bàbá rẹ̀ tó jíǹde padà lẹ́yìn EndSARS
- Kí ló ṣokùnfà iná tó sọ ọjà Shasha dahoro n'Ibadan?
- Ilé-ẹjọ́ yí ẹjọ́ DPO ọlọ́pàá tó ju télọ̀ sátìmọ́lé torí ó ba aṣọ rẹ̀ jẹ́ dànù
- Makinde loun ní ìbéèrè láti bi Ajimobi lórí aṣemáṣe iṣẹ́ àgbàṣe, ni kọmíṣọ́nà Ajimobi kan bá gbarata
O ni botilẹ jẹ pe ajakalẹ aarun COVID-19 ati awọn nnkan mii ṣe idiwo fun eto igbaniwọle sinu ikọ naa, lẹyin ọrẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ Amọtẹkun ti o to bi i ẹgbẹrun kan o le lẹẹdẹgbẹta ni wọn pada gba wọle ti wọn ti ṣe
idanilẹkọ fun bayii.
Makinde fi kun ọrọ rẹ pe ọna kan gboogi lati wa ojutu si iṣoro eto aabo ni idasilẹ ikọ Amọtẹkun.O ni ikọ olominira Amọtẹkun ṣugbọn wọn o maa kun awọn ẹṣọ aabo ijọba apapọ to ku lọwọ lati gbogun ti awọn ajinigbe ati awọn ọdaran mii gẹgẹ bi wọn o ṣe maa ṣe iwọde lọsan ati loru.
Gomina ipinlẹ Ọyọ fi idaniloju han pe dundun lọsan yoo so lẹyin agbekalẹ ikọ Amọtẹkun.Lara awọn to pejupesẹ sibi eto naa ni adara ikọ Amọtẹkun, Ajagunfẹyinti Ajibola Kunle Togun, Ajagunfẹyinti Olayanju Olayinka, ladelade-loyeloye ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ.