You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EFCC ṣàlàyé bí afurasí náà ṣe lu ará Amẹ́ríkà kan ní jìbìtì $135,800 ati $47,000
Ọwọ ajọ EFCC, ẹka ti ipinlẹ Enugu ti tẹ oluṣọagutan kan ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI ti n tọpinpin rẹ tẹlẹ.
Afurasi naa, Kelechi Anozie, to jẹ oludasilẹ ijọ Praying City Church to wa niluu Oweri, ko si gbaga EFFC lori ẹsun lilu jibiti lori ayelujara ati wiwọ ike, ti ọpọ eeyan mọ si 'waya-waya.'
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ajọ FBI ti n wa pasitọ naa ṣaaju akoko yii ki awọn to kẹfin rẹ niluu Enugu.
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
- Gómìnà ànà ní Anambra, Obiano bọ́ sí gbaga EFCC lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tó gbé ìjọba sílẹ̀
- Ogunsua ìlú Modakeke, Ọba Moses Oladejo Oyediran wàjà
- Ẹ wo àṣírí tó wà nìdìí ìròyìn pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì kò fún ọmọ Nàìjíríà ní “visa” mọ́?
- Wọ́n tan bàbá 85 kúrò nílé, fọ́ igi mọ lórí, ju òkú rẹ̀ sétí odò l‘Ogun
- Krìsìtẹ́nì àti Mùsùlùmí, ètò ọba jíjẹ àti ìsìnkú ọba kò kàn yín, ẹ jìnnà si - Oníṣẹ̀ṣe l'Ogun
- Àwọn tó ń bá mi du ipò ààrẹ ni kò mọ ohun tó kàn fún Nàìjíríà - Tinubu
- Nàíjíráà kàn ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, lóòtọ́ọ́ ló yẹ kí ìpàdé àpérò ọmọ Nàíjíríà wà - Ọba Tejuosho
- 1200 èèyàn rì sábẹ́ ilẹ̀ bí Russia ṣe yin àdó ikú mọ́ gbọ̀ngàn nlá kan ní Ukraine
Ninu atẹjade kan ti agbẹsunsọ EFCC, Wilson Uwujaren fi lede, o ni oludasilẹ naa atawọn afurasi mii, Valentine Iro, Ekene Ekechukwu, Bright Azubuike, ati Ifeanyi Junior ni awọn n wa.
Uwujaren ni ẹsun pe wọn lu ẹnikan to n gbe niluu Illinlois, nilẹ Amẹrika ni jibiti ayelujara, ti iye rẹ to $135,800 ati $47,000 ni awn n wa wọn fun.
Afurasi onijibiti ori ayelujara dero ẹwọn:
Ni iroyin miran, adajọ Muhammed Sani ti ile ẹjọ giga kan niluu Ilorin ti sọ ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Taiwo Emmanuel si ẹwọn oṣu mẹfa lẹyin to jẹbi ẹsun fifi ara rẹ pe ẹlomiran.
Afurasi naa wa lara awọn onijibiti ayelujara ti EFCC fi ṣikun ofin mu niluu Ogbomosho loṣu Kẹwaa, ọdun to kọja.
Emmanuel sọ fun awọn to n gba pe oun jẹ oniṣowo ati agbasẹṣe to n fi ilu Amẹrika ṣe igbugbe lọna ati fi ọna ẹburu gba owo lọwọ wọn.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Sani sọ pe ẹri to wa niwaju ile ẹjọ naa fi han gedegbe pe lootọ ni Emmanuel ṣe ohun ti wọn fi ẹsun rẹ kan.
Adajọ naa fi kun pe ẹsun naa lodi si ofin to rọ mọ lilu jibiti ori ayelujara ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015.
Lara awọn dukia ti EFCC ka mọ afurasi naa lọwọ ni ẹrọ ilewọ iPhone X ati kọmputa alagbeka Lenovo kan.