Osun Monarch: Ogunsua ìlú Modakeke, Ọba Moses Oladejo Oyediran wàjà

Ọjọ́ ọjọ́ kan làá joyin, ọjọ́ ọjọ́ kan làá jàdò, ọjọ́ ọjọ́ kan la ó sùn tí a kò jí tí iná yóò dilẹ̀ lẹ́yìn asunṣejẹ.

Ogunsua ti ìlú Modakeke, Ọba Moses Oladejo Oyediran, Ajombadi kẹta ti lọ darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.

Oba Oyediran gẹ́gẹ́ bí ìròyìn láti ààfin ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wàjà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí.

Nínú oṣù kẹwàá, ọdún 2018 ni Kabiesi náà gun orí àpèrè àwọn baba rẹ̀ lẹni ọdún méjìléláàdọ́rin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ta ni Oba Oyediran?

Ọba Moses Oladejo Oyediran jẹ ọmọ bíbí agboolé Ajombadi ní ìlú Modakeke, ìpínlẹ̀ Osun.

Ní ọdún 2018 ní Oba Oyediran gbadé gẹ́gẹ́ bí Ogunsua ti ìlú Modakeke ní ààfi ìlú náà tó wà ní Ita Merin lẹ́yìn tí Ọba Francis Adedoyin láti ìdílé Olaogbin gbésẹ̀.

Ọba Oyediran ni Balogun ìlú Modakeke kó tó gbadé gẹ́gẹ́ bí Ogunsua gẹ́gẹ́ bí òfin ìlú Modakeke ṣe là á kalẹ̀ pé ẹni tó bá jẹ́ Balogun ní yóò di Ogunsua.