PDP Primaries: PDP gbé ìwé ẹ̀rí àṣeyege fún Ademola Adeleke láti díje gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Idibo PDP l'Osun

Eremọde lasan ni - Igun Dọtun Babayẹmi

Amọṣa igun keji ninu ẹgbẹ oṣelu PDP to fa Dọtun Babayẹmi kalẹ gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn fọwọleran n wo ibi ti kangunkangun ọrọ naa yoo kangun si ni nitori pe awọn ni ile ẹjọ fun ni aṣẹ lati fa oludije ẹgbẹ naa kalẹ.

Dotun Babayemi

Oríṣun àwòrán, @Babayemi

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹnusọ fun igun ti Dọtun Babayẹmi, Alagba Kayọde Ọladeji ṣalaye pe ko sewu loko fun awọn afi giri aparo.

Sẹnetọ Adeleke n gba iwe ẹri aṣeyege idibo abẹnu lọwọ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu ati Ambasadọ Taofeeq Arapaja

Oríṣun àwòrán, Pdp

PDP gbé ìwé ẹ̀rí àṣeyege fún Ademola Adeleke láti díje gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Ademọla Adeleke ni igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ oṣelu PDP fun ni iwe ẹri gẹgẹ bi omo oye ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo apapọ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu ati iagbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹkun iwọ oorun guusu, Ambasadọ Taofeeq Arapaja lo gbe iwe ẹri aṣeyege idibo abẹnu naa le Sẹnetọ Ademọla Adeleke lọwọ.

L'owurọ Ọjọbọ, ọjọ kẹẹwa oṣu keta ọdun yii ni Ademọla Adeleke ati alaga ẹgbẹ oṣelu PDP n'ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Sunday Bisi gunlẹ si olu ile ẹgbẹ oṣelu naa to n bẹ ni agbegbe Wadata, niluu Abuja.

Adeleke ati iwe ẹri rẹ

Oríṣun àwòrán, Pdp

Igun Dotun Babayemi tun salaye pe:

O ni nitori pe gbogbo ọna ti ofin la kalẹ ni awọn tọ.

Ati pe, o si daju pe lẹyin o rẹyin Dọtun Babayẹmi ni yoo dije fun PDP nibi eto idibo gomina nipinlẹ Ọṣun eleyii ti yoo waye oṣu keje ọdun 2022.

Bawo lọrọ naa ṣe wọ wa lati ipilẹ?

Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2022 ni idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun waye lati le e mọ ẹni ti yoo dije fun ipo gomina ipinlẹ naa labẹaṣia ẹgbẹ ọselu ọhun.

Amọṣa kakaki eto naa waye loju kan, igun meji ọtọọtọ lo ṣe eto idibo abẹnu tiwọn nibudo ọtọọtọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run kí Krìstẹ́ni jẹ Ọba ilẹ̀ Yorùba? Pásítọ̀ ìjọ Deeper Life sọ ìran tó rí tó fi gbà láti jẹ Ọba

Awọn igun to fara mọ Sẹnetọ Ademọla Adeleke wa ni papa iṣire ilu Oṣogbo nibi ti wọn ti yan Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

Bakan naa lawọn tọ rọgbọku le Dọtun Babayẹmi pẹlu ṣe tiwọn ni ibudo igbalejo WOCDIF nib ni wn si ti dibo yan Dọtun Babayẹmi

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ó yẹ kí Buhari pé Igboho bíì bàbá s'ọ́mọ ni; Láyé! Kò sẹ́ni tí kò ni jèrè i

Iṣẹlẹ naa lo ṣafihan aisi iṣọkan eyi to ti n gbilẹ lẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun fun igba diẹ bayii.