You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Assault on LASTMA officers: Ìjọba Eko tí ṣetán láti f'imú ẹnikẹ́ni tó bá tún fi ìyà jẹ òṣìṣẹ́ LASTMA dánrin
Ọga agba ajọ to ri si lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA, Ọgbẹni Bolaji Oreagba ti bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn eeyan kan ṣe n ṣe ikọlu sawọn oṣiṣẹ LATSMA lẹnu iṣẹ.
Ninu atẹjade kan ti ajọ LASTMA fi sita, Oreagba ni awọn awakọ to n tapa sofin iwakọ loju popo lo huwa ipa sawọn oṣiṣẹ LASTMA.
Oreagba ni ijọba ipinlẹ Eko ko ni fi oju ire wo ẹnikẹni to ba tun fiya jẹ oṣiṣẹ ajọ LASTMA lati akoko yii lọ.
Oreagba ni ''lati akoko yii lọ, ẹnikẹni to ba tun ṣe ikọlu tabi fiya jẹ awọn oṣiṣẹ LASTMA yoo foju wina ofin nipinlẹ Eko.''
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Ǹjẹ́ ó mọ̀ nípa álífábẹ́ẹ̀tì Oduduwa? Wo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jáde lórí rẹ̀ ní Benin Republic
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti bẹ́ sílẹ̀ láàrín Pasuma àti 'Manager' rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó?
- Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé o fí agídí bá ọmọdé lòpọ̀
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi buwọ́lu ₦30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ
- Amotekun Ondo gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ àjàgbé tó ń kó àwọn ọ̀dọ́ 63 láti Gombe lọ sí Eko
- Ẹ̀yin ará ìlú ẹ má bìnú, kìí ṣe pé a mọ̀ọ́mọ̀ kó epo tí kò dáa wọ Naijiria
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
- Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọmọ ọdún kan àti oṣù méje pa ní ìpínlẹ̀ Delta, O bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá
Idi ree ti ọga ajọ LASTMA fi binu tan
Oreagba tutọ soke, o si foju gba a nitori iṣẹlẹ kan ninu eyi ti wọn ti fẹsun kan awakọ Korope kan, Ibrahim Yusuf, pe o fẹ ṣekupa oṣiṣẹ LASTMA, Awotola Victor, to n dari ọkọ lopopona Ojodu Berger si Ogba.
Lọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2022 yii ni oṣiṣẹ LASTMA naa fẹ mu Yusuf lẹyin ti wọn lo n tapa sofin iwakọ lopopona ọhun.
Oreagba ni ikọlu sawọn oṣiṣẹ ijọba ti wa n pọju bayii, o ni ijọba naa ti ṣetan lati fopin si iwa yii nigba gbigbe iru awọn eeyan bẹẹ lọ si ileẹjọ.
Bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ niyii
Awakọ Korope ọhun, Yusuf ni wọn lo da wahala silẹ ti o si dina mawọn awakọ mii lati kọja lagbegbe ilegbe River Valley ni Berger,
Wọn ni Yusuf ko ya si ibi kan ninu gbogbo iyana to wa ni River Valley, eleyii to jẹ ki awọn LASTMA mu ọkọ rẹ.
Bayii ni Yusuf poora bi iso, o kuku tun pada wa amọ pẹlu ọbẹ lọwọ rẹ lo pada si iyalẹnu awọn eeyan to wa nibẹ.
Ọbẹ yii naa ni a gbọ pe o fi ṣe oṣiṣẹ LASTMA leṣe lori ati ọrun.
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjà ọ̀dàn
- Orílẹ̀-èdè méjìlá pàṣẹ̀ pé kí àwọn eèyàn wọn kúrò ní Ukraine nítorí ogun Russia tó súnmọ́ tòsí
- "Ẹ̀yin obìnrin, ẹ fi òdòdó ṣe ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́ fún ọkùnrin dípò kẹ gbà kó já òdòdó ara yín"
- Tí o bá ń pẹ́ jẹun alẹ́, o lè ní àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti asétọ̀
- Wo ǹkan márùn ún tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fẹ́ ní 'Valentine' 2022
Yusuf fẹsẹ fẹẹ lẹyin to ṣe ohun to ṣe tan ṣugbọn wọn mu ọkọ rẹ to n wa.
Lọjọ Aiku to jẹ ọjọ keji ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni ọkan lara awọn alaga awọn awakọ Korope, ọkunrin naa si ti wa ni atimọle ni agọ ọlọpaa to wa ni Ojodu.
Yusuf yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.
Ọga agba LASTMA wa rọ gbogbo awakọ ni ipinlẹ Eko lati maa tẹle ofin iwakọ, bi bẹẹ kọ wọn o foju wina ofin.