Africa Eye: Ọpọ̀ obìnrin ní wọn pa, fipá bá lòpọ̀ tàbí ṣe léṣe lásìkò ìgbélé Coronavirus
Nigba ti ijọba kede igbele ọlọsẹ meji ni orilẹede Kenya lati dẹkun ọwọja arun Coronavirus ni ọdun 2021, se ni aiwa ipa tawọn eeyan kan n hu si awọn obinrin foju han sita.
Koda, ọwọja iwa ipa sawọn obinrin naa lọ soke tobẹẹ gẹ debi pe ọpọ awọn obinrin lo jade laye, wọn fi ipa ba awọn miran lopọ nigba ti awọn miran di alaabọ ara.
Koda, se ni ipe fun iranwọ ati idoola ẹmi n peleke si pẹlu ida ọọdunrun lasiko igbele Covid-19 naa.
- Ǹjẹ́ sísan owó ìdóòlà láti gba àwọn ọmọdé lọ́wọ́ ajínigbé dárá tó? BBC Africa Eye tú àṣírí síta
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- Ẹ̀rí tuntun BBC Africa Eye yìí tú àṣírí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan nínú ìbúgbàmù Abule Ado
- "Shrine" ni wọ́n ń pé ọ́fíísì wa táa ti ń sanwó òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì", BBC Africa Eye tú àṣírí wọn
- Àkàrà tú sépo! Ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ BBC tú àṣírí bí SARS ṣe ń fìyà jẹ aráàlú
- Mi ò mọ nkankan nípa ọmọ Nàìjíríà tó n fi àwọn obìnrin ṣe aṣẹ́wó ní India - Abike Dabiri
- Ìwádìí fídíò ayélujára tú àṣìrì ìpànìyàn Boko Haram
Ọkọ sa iyawo rẹ ni ada ni ẹsẹ ati ọwọ, to si tun sa ọmọ wọn ọdun mẹfa pa:
Ninu fidio yii, a ri obinrin kan ti oun ati ọkọ rẹ ti yẹra fun ara wọn amọ ti ọkọ n beere pe ki obinrin naa ko pada wa si ọdọ oun, ti obinrin naa ko si gba.
Lẹyin eyi nni ọkunrin naa lọba iyawo rẹ nile lasiko igbele Covid-19, o sa ni ada ni ẹsẹ mejeeji, ge ni ọwọ, to si tun sa ọmọ wọn, tii se ọmọ ọdun mẹfa ni ada pa.
Isẹlẹ iwa ipa ni Kenya le ni ẹgbẹrun marun laarin ọdun kansoso:
Laarin ọdun kan soso, orilẹede Kenya ti se akọsilẹ awọn isẹlẹ to le ni ẹgbẹrun marun eyi to ni se pẹlu iwa ipa si awọn obinrin.
Amọ awọn ajafẹtọ ẹni ni awọn isẹlẹ iwa ipa naa ju iye akọsilẹ yii lọ ta ba wo ẹru, idẹyẹsi ati aini igbẹkẹle ninu ẹni tawọn araalu ti ni nipa isẹlẹ naa.
Koda, wọn ni awọn araalu ko ni igbẹkẹle kankan mọ ninu awọn ọlọpaa orilẹede naa, idi si ree ti wọn ko fi lọ fi ọpọ irufẹ isẹlẹ iwa ipa yii to ileesẹ ọlọpaa leti.





