You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Timothy Adegoke: Agbẹjọ́rò Adedoyin ní kí ọlọ́pàá ṣe ìwádìí bí wọn ṣe sin Adegoke, oníbàráà òun kò mọ̀ nípa rẹ̀
O dabi ẹni pe ọrọ tun ti fẹ bẹyin yọ lori iwadii iku akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke to ku si ile ìtura Hilton hotel ni Ile Ife.
Ọjọru ni agbejoro Ramon Adegoke to ni ile itura Hilton, Abiodun Williams sọ pe, iwadii ti fihan pe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ife lo sin Adegoke pẹlu aṣẹ lati ọdọ awọn ọlọpaa.
Williams wa rọ awọn ọlọpaa lati gbe ọrọ ti oun sọ yii yẹwo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n fi jí mi gbé tí wọ́n ń fipá bá mi lòpọ̀ títí tó fi di oyún'
- Ṣé lóòótọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ girama ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa akẹ́kọ̀ọ́ míì l'Eko?
- Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ fi Sunday Igboho sílẹ̀, Agbekoya yarí
- 'Gbogbo ọlọ́pàá tó ń gbégidínà lọ́nà àìtọ́, ẹ yọ wọ́n kúrò'
- Mo fún òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà di December 18 láti fi ipò tó wà sílẹ̀ - Gómìnà Fayemi
- Bí àdúrà ọjọ́ kẹjọ àti ayẹyẹ òkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí méje tó ń pa èèyàn ṣe ètùtù ọlà l‘Ogun
- Obìnrin ẹni ọdún 28 kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ariwo sọ!
Ninu iwe ti o fi ṣọwọ si kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ọsun, Williams ṣalaye pe awọn eeyan to sun mọ agbegbe ti wọn ju oku Adegoke si, lo ta awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ Ife lolobo.
O ni awọn ijọba ibilẹ yii lo kan sí awọn ọlọpaa nipa oku naa, ti wọn si fun wọn ni iyọnda lati sin oku naa.
Williams wa rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe agbeyẹwo ọrọ yii lati le mọ ipa ti gbogbo awọn afurasi ko lori ọrọ iku Adegoke.
"Iwadii mi fidi rẹ múlẹ pe awọn eeyan kan ṣe fídíò bi wọn ṣe sin oku akẹkọọ OAU yii.
Ti ileeṣẹ ọlọpaa ba si ṣe iwadii lori ọna ti wọn gba sin Timothy Adegoke, o tubọ maa jẹ ko han pe onibara mi ko mọ nipa iku rẹ, Williams lo sọ bẹẹ.
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- Àlàyé ọlọ́pàá Osun rèé lórí ọ̀nà tí Rahmon Adedoyin gbà ká ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínu fọ́nrán ohùn tó lu ayélujára pa
- Wo Sẹ́nétọ̀ tó fẹ́ gbé bùkátọ̀ iléẹ̀kọ́ ìbejì Timithy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
Ẹwẹ, alaga ijọba Ifẹ, Họnọrebu Olayera Elugbaju sọ fun iwe iroyin Nation lọjọ Ẹti to lọ pé, irọ ni iroyin kan to sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa kan lori iku Adegoke.
Họnọrebu Elugbaju ni "ko si oṣiṣẹ ijọba ibilẹ yii kankan ti awọn ọlọpaa mu.
Amọ, mi o le sọ bo ya awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ife wa lara awon to sin Timothy Adegoke ayafi ti mo ba wo akọsilẹ nipa bi a ṣe sin oku lasiko iku akẹkọọ fasiti OAU yii."