You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ekiti Governorship Election: Gómìnà Fayemi ní kí òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà fi ipò sílẹ̀
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ni ijọba rẹ lati fi ipo silẹ ti wọn ba fẹ du ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti.
Ninu atẹjade gba ọwọ agbẹnusọ fun gomina Fayemi, Yinka Oyebode ni wọn ti fi lede pe Ọjọ Kẹrinla, Osu Kejila ni gomina fun wọn da lati fi ipo silẹ ni ijọba oun.
Oyebode ni gomina gbe igbesẹ naa lọna ati rii pe awọn oṣiṣẹ to wa ni ijọba oun ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lai si magomago.
Bakan naa ni wọn fi kun un pe eyi tẹlẹ aṣẹ eto idibo lorilẹede Naijiria, paapaa saaju idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti.
''Lọna ati tẹle aṣẹ Ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo bẹrẹ idibo abẹle ni Oṣu Kini ọdun 2022, ti idibo sipo gomina naa yoo si waye ni Osu Kẹfa, ọdun 2022 kan naa.''
Lara awọn to wa ni ijọba gomina Fayemi ti awọn eniyan lero wi pe wọn fẹ fu ipo yii ni Akọwe ijọba, Biodun Oyebanji, Adari oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti, Biodun Ọmọlẹyẹ, kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ, Bamidele Faparusi ati oluranlọwọ pataki si gomina, Ọjọgbọn Bolaji Aluko laarin awọn miran.
- Obìnrin ẹni ọdún 28 kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ariwo sọ!
- Agbófinró ti ọ̀pọ̀ òṣìsẹ́ ọba mọ́ ìta ọ́ọ́físì torí àìgba àbẹ́rẹ́ àjẹsára
- 'Omicron ti wọ Nàìjíríà o', ìjọba àpapọ̀ kéde; Canada bẹ́gi dínà àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ wọlé
- A kò faramọ́ àbájáde ''Endsars Panel Report'', kò sí ẹni tó kú ní Lekki Tollgate sẹ́ẹ̀, "White paper" wa rèé - Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko
- Buhari tí gba àkóso NINAS, n kò ṣe mọ́ - Akintoye kọ̀wé-fipò sílẹ̀
- Bimbo Oshin Ṣàlàyé lórí bí ọkọ rẹ ṣe kú lẹ́yìn ìjáde opó
- Bimpe Oyebade sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí àwọn èèyàn tó ń lọgun pé ó lóyún