Endsars Panel Report: A kò faramọ́ àbájáde ìwádíi èsì Endsars Panel Report, kò sí ẹni tó kú ní Lekki Tollgate - Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti fi abajade iwadii wọn lede, iyen White Paper lori esi iwadii igbimọ ti ijọba gbekalẹ lori iṣekupani to waye ni Lekki Tollgate lasiko Endsars ni ọdun 2020.

Esi ijọba naa ti wọn pe ni ''White Paper'' lo tabuku iwadii igbimọ ọlọfintoto naa ti wọn gbe jade lori iṣẹlẹ to waye gan an ni Ọgunjọ, Osu Kẹwaa, ọdun 2020.

Ninu abajade ti igbimọ iwadii Endsars Panel gbejade ni wọn ti parọwa si ijọba lori igbesẹ mejilelọgbọn ti ijọba gbọdọ gbe lati ri pe otitọ jọba lori iṣẹlẹ to waye ni asiko Endsars.

Iwadii igbimọ naa ni ki ijọba ri daju pe wọn kọ agbegbe kan fun iranti manigbagbe fun awọn ti ẹmi wọn sọnu ati awọn ti wọn faragba ninu iṣẹlẹ naa ni ọdun 2020.

Amọ esi ti ijọba ipinlẹ eko fun igbimọ naa ni wi pe '' awọn ko le e gba imọran naa wọle nitori esi ayẹwo ti dokita onimọ nipa ayẹwo oku, ọjọgbọn Obafunwa gbe jade ni oku eniyan mẹta nikan ni wọn gbeyẹwo lati Lekki tollgate, ti ẹyọkan si jẹ ẹni ti wọn yinbọn ba.

''Iwadii igbimọ to sọ pe eniyan mẹsan ku ni Lekki Tollgate ni Ogunjọ, Osu Kẹwaa, ọdun 2020 tilẹ ba ni ninu jẹ nitori awọn orukọ ti wọn fi sibẹ pe wọn ku, ko ba arajọra.''

''Awọn orukọ to wa ni oju iwe 297-298 ko salaye iru iku to pa awọn eniyan yii ti ko si fisi mulẹ rara.

Bakan naa ni orukọ Kolade Salem waye ni eemeji ti Folorunsho Olabisi naa waye ni ẹẹmeji, ti wọn si tun fi orukọ ẹlẹri Nathaniel Solomon sibẹ gẹgẹ bi ẹni to ku''

''Amọ Nathaniel kan wa jẹri ni pe aburo oun Abata Soloma wa lara awọn to ku ni asiko Endsars''.

''Oku ẹnikan pere ti wọn ri lẹyin iṣẹlẹ Endsars ni wọn ri ni ni ọjọ keji iṣẹlẹ naa ti iṣẹde bẹrẹ lai si aridaju ẹni to yinbọn pa.''

''O tun fihan gbangba pe iwadii wọn ko fi ẹsẹ mulẹ nitori ẹnikan pere ni wọn kọ si abẹ orukọ rẹ pe o ti jade laye ninu awọn mẹsan ti wọn fi orukọ wọn lede.''

Ijọba ipinlẹ Eko wa fikun un pe awọn ko ni le e tẹwọ gba iwadii igbimọ naa nitori ko fi ẹṣẹmulẹ, ko si muna doko.

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn yoo fi to ijọba apapọ leti gbogbo erongba igbimọ iwadii naa lori ipa ti ikọ ọmọogun Naijiria ko lori iṣẹlẹ naa ati ọna abayọ amọ ijọba ipinlẹ ko ni aṣẹ lori ikọ ọmọogun lorilẹede Naijiria.