Baba Suwe: Yomi Fabiyi ṣe àlàyé ìdí tí kò ṣe yọjú síbi ìsìnkú Omidina

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba lo pa a lowe pe ba ku laa dere, eeyan ko suwọn ni aaye.

Awọn ololufe gbajumọ adẹrinposonu nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe ti kede ọna ti wọn fẹ gba bu ọwọ nla fun akọni osere naa.

Awọn ololufẹ Baba Suwe naa to wa nilu London ni United Kingdom si lo n se agbatẹru eto imọyi naa fun oloogbe Omidina.

Atẹjade kan ti awọn ọkan lara awọn ololufẹ Baba Suwe, Yomi Fabiyi to wa nilu Ọba fisita sisọ loju rẹ pe, awọn ti la oniruuru eto silẹ lati se ẹyẹ ikẹyin fun Baba Suwe.

Fidio kan ti Yomi Fabiyi se soju opo Instagram rẹ lo sisọ loju rẹ pe, oun ko fẹ ko sọwọ awọn eeyan to n wa oun ni Naijiria, ni oun ko se wa sibi isinku Baba Suwe.

"Ẹ mọ awọn araabi, ti wọn ti n gbe igbesẹ lati mu oluwarẹ tẹlẹ tẹlẹ, ki oluwarẹ tun wa lọ ko si wọn lọwọ.

Ti mo ba tun wa si Naijiria lati yọju sibi isinku Baba Suwe, maa gbe ile fun ayẹwo Covid-19 fun ọjọ mẹwa, yoo si se akoba fun mi lati wa se ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe naa.

Yatọ si eyi, o yẹ ki eeyan maa tẹle ofin, a dupẹ fun ewu ti Ọlọrun jẹ ko fo wa da, bi wọn pe ogun, bi wn pe igba, awa naa laa maa jẹri wọn.

Maa lọ si ibi isin ikẹyin ti yoo waye ni Manchester ati UK, amọ o dun mi pe n ko le peju sibi isinku ti Naijiria."

O ni ọjọbọ, ọjọ Keji osu Kejila ọdun 2021 ni eto imọyi fun Baba Suwe yoo waye ni Manchester nigba ti ti London yoo waye ni ọjọ keji rẹ, tii se ọjọ Ẹti.

Lara awọn ẹyẹ ti wọn fẹ se fun eto imọyi naa ni titan abẹla, tito ni ọwọọwọ ati sise isin idagbere fun lati ki osere tiata naa pe o digbose.

Mosalasi Ar-Rahman to wa ni ojule karun si ikẹsan, opopona Record ni SE15 ITL ni London ni isin idagbaere ọhun yoo si ti waye.

Yomi Fabiyi fikun pe aago mẹta ọsan si marun irọlẹ, ni isin naa yoo maa waye.

Wọn wa n rọ awọn ololufẹ Baba Suwe to wa ni London ati agbegbe rẹ, lati peju sibi eto isin idagbere naa.

Bakan naa ni Fabiyi wa n dupẹ lọwọ awọn eeyan ti wọn n daro ẹni rere to lọ naa pe ọdun yoo jinna sira wọn.