You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
ENDSARS Panel Report: Wo ohun tó wà nínú ìwé ìjọba lórí àbọ̀ ìwádìí ìwọ́de EndSARS
Àwọn ọmọ Naijiria ko fẹnu ko lori iwe ilana ti ijoba yoo gba lati yanju awọn koko tó jẹyọ ninu abajade ijoko igbimọ to gbọ ẹjọ iwa ipa ologun ati ọlọpa si awọn oluwọde EndSARS ni Lekki.
Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwoolu lo gbe igbimọ naa kalẹ lọdun to kọja lati gbọ ehonu awọn eeyan ti ọlọpaa SARS ti ṣe basubasu, eyi ti adajọ Doris Okuwobi jẹ alaga rẹ.
Ni ọjọ kẹẹdogun oṣu Kọkanla ni igbimọ naa gbe abajade iwadii rẹ silẹ fun gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, abọ naa si pin si meji.
Abọ akọkọ ni ti iwa ipa awọn ọlọpaa SARS si araalu lapapọ nigba ti abọ iwadii keji da lori ipaniyan to waye ni Lekki toll gate.
Ijọba Eko ti wa gba mọkanla ninu aba igbimọ to gbọ ẹjọ ọlọpaa SARS naa wọle, amọ o kọ ọkan ninu rẹ nigba to ṣe atunṣe si mẹfa nibẹ.
Gẹgẹ bi alaye ijọba, mẹrinla ninu àwọn aba naa ko si lọwọ ìjọba ipinlẹ lati se amusẹ rẹ ati pe àwọn yoo fi sọwọ si ijọba apapọ lati gbe yẹwo.
Eyi si ni awọn ohun pataki to wa ninu iwe asẹ ijọba to gbe kalẹ ni ọjọ Isẹgun lori abọ igbimọ iwadi iwọde EndSARS ati ipaniyan to waye ni Lekki.
Koko meje to wa ninu iwe asẹ ijọba nipa abọ iwadii igbimọ iwọde EndSARS agbekalẹ ẹlẹni mẹrin naa eyi to gba oju iwe mẹrinlelogun ree:
1. Iwadii ijoko Endsars fidi rẹ mulẹ pe eniyan mẹsan ti wọn ni ìbọn awọn soja pa ni ogunjọ osu kẹwa, ọdún 2020 ni iloro Lekki(Lekki Toll Gate) ko ni ẹri to daju ahesọ lasan ni.
2. Lilọ bibọ ati aifẹnuko igbimọ lori iye eniyan to ku ni Toll gate ninu osu kewaa ọdun 2020 ati nnkan ti o fa iku wọn ti mu ki abajade igbimọ jẹ eyi ti ko ṣe e gbára lé, nitori naa ijọba ko le gbaa wọlé.
3. Gẹgẹ bi ijọba ṣe sọ : eniyan kan ṣoṣo ti ìbọn ba ni wọn gbe kuro ni Lekki Toll Gate ni nnkan bi aago meje kọja lẹyin ti isede ti bẹrẹ, ẹni naa si farapa ni( ẹri eyi si wa ni oju iwe 99) Ati pe ko si ẹri kan to daju bayii pe ẹni bayii lo yin nibọn.
Nipa aba ti igbimọ naa gbekalẹ, wọn ni o yẹ ki wọn da sẹria fun awọn ọmọogun to lọ to fi mọ Col. S.O Bello ati Major General Godwin Umelo ti o kọ lati wa siwaju igbimọ igbẹjọ, nipasẹ eyi to mu iwadii naa nira
Ijọba ipinlẹ ni oun yoo fi eyi sọwọ si ijọba apapọ, igbimọ alasẹ ati àwọn olori ile iṣẹ ọmọogun lati gbe igbesẹ.
4. Lara aba ti igbimọ naa da ni pe ki wọn fi gbọngan Lekki toll plaza ṣe gbọngan melegbagbe fun iwọde Endsars nipa pipe ibẹ ni "EndSars Tollgate, sugbọn ìjọba ni kaka bẹẹ oun yoo se agbekalẹ adugbo kan ti wọn yoo ma pe ni " Peace Park"
5. Lara aba igbimọ ni pe ki gbogbo ogunjọ osu kẹwa ma jẹ Irina ofẹ lati kọja ni Tollgate, ìjọba ni oun faramọ ki idariji ati Itesiwaju le wa, ṣugbọn oun ko le gba ki wọn maa pe ọjọ naa ni ayajọ Endsars nitori ijọba ipinlẹ ko lagbara lati da ayajọ ọjọ kan silẹ, ijọba apapọ lo ni iru agbára bẹẹ nitori naa wọn yoo fi sọwọ si ijọba
6. Nipa awọn aba miiran ti igbimọ ṣe, ìjọba ipinlẹ Eko ni ko ni agbara lori awọn ọrọ abẹle nipa ó ọlọpaa ati pe awọn yoo fi aba naa sọwọ si àwọn ajọ ti ọrọ kan bi ijọba apapọ, igbimọ alaṣẹ ìjọba, ajọ to n mojuto ọrọ ọlọpaa ati ile isẹ ọlọpaa
7. Ìjọba ipinlẹ Eko dupẹ lọwọ gbogbo awọn òṣìṣẹ́ ilera ati ile iwosan to tọju awọn farapa lasiko ifehonuhan
O ni ijọba yoo tesiwaju lati ma fi ikuluku pẹlu awọn ọdọ àwọn yoo se si maa se agbekalẹ awọn eto mìíràn to nise pẹlu ifikuluku pẹlu ọdọ ati ọlọpaa, ilana igbe aye alafia awọn ọdọ
Bakan naa ni ijọba fi kun pe oun yoo se agbekalẹ ajọ/igbimọ ti yoo maa moju iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Ẹ forí jìn mí, mí o lè bá Gómìnà rìnrìn àlàáfíà kánkan-Debo Macaroni
Awọn gbajumọ ori ayelujara ti Gomina Babajide SanwoOlu ipinlẹ Eko kesi pe ki wọn kọwọ rinrin alaafia pẹlu rẹ ti fesi pe awọn ko le baa Gomina rinrin kankan.
Debo Mr Macaroni ati Falz the bad guy to fi mọ Seun Kuti wa lara awọn ti Gomina darukọ lasiko to n ba araalu sọrọ ṣaaju gbigbe jade iwe lori iwadii igbimọ ENDSARS ni Eko.
Ni tirẹ Debo Macaroni sọ pe oun fi tọwọ tọwọ sọ pe oun ko ni kopa ninu irin ti Gomina pe oun si.
Loju opo rẹ ni Instagram lo ti fi ọrọ yi sita.
Gẹgẹ bo ti ṣe sọ, irin toun rin kẹyin ijiya lo ba de ati pe ti Gomina ba nifẹ si alaafia igbesẹ to yẹ ni ko ṣamulo abajade iwadii igbimọ ti wọn gbe kalẹ.
''Ti mo ba fẹ rinrin alaafi Gym ni maa gba lọ. Irin alaafia tawọn kan rin ti wọn fi pa wọn tawọn ẹlomiran ṣi yi wa lẹwọn?''
O tẹsiwaju pe ijọba ni lati jẹ olootọ nipa gbigba pe awọn kuna ki wọn si tọrọ aforijin lọwọ araalu lori aṣiṣe wọn.
Ninu esi tirẹ, Folarin Falana ti ọpọ mọ si Falz the bad guy ni ''awada lasan ni ọrọ irin alaafia yi eleyi ti ko bọwọ fun ni''
''O ni wọn pa awọn eeyan ti ko si si idajọ ododo lori eleyi lati nkan bi ọdun kan.Bawo la se le ri alaafia lalae ṣe idajọ ododo?''
Falz sọ pe titi di asiko yi, wọn ṣi n gba ẹmi awọn ọdọ Naijiria lati ọwọ awọn ọmọ ogun Naijiria.
Ọfisi Gomina ko ti fesi si ọr ti wọn sọ yi bẹẹ si ni a ko ti ri esi iwaadi igbimọ ENDSARS ti Gomina sọ pe awọn yoo gbe jade lọjọ Iṣẹgun.
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, ìjọba Eko máa gbé èsì ''white paper'' jáde lórí ìwádìí ìgbìmọ̀ ENDSARS lónìí
Gomina Babajide SanwoOlu ipinlẹ Eko ti sọ pe iwe esi ijọba lori iwadii igbimọ ENDSARS yoo jade loni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun.
Lasiko to n ba awọn araalu sọrọ nile ijọba lo fi ọrọ yi lede.
Sanwo Olu ni igbesẹ yi yoo jẹ ọna kan gbogi lati mu opin ba iṣẹlẹ ikọlu to waye ni Lekki Tollgate.
Bẹẹ lo ni yoo jẹ ki ijọba ati araalu wa wọrọkọ fi ṣada lori ọna ati tẹsiwaju nipa idagbasoke ipinlẹ Eko.
O ti to ọjọ mẹta tawọn araalu ati eeyan Naijiria lapapọ ti n gbẹ oungbẹ esi iwadii yi toun ti pe ẹda abajade igbimọ naa kan ti ṣaaju lu sita.
SanwoOlu ni o di dandan ki awọn araalu Eko wa ọna lati gbe igbepọ alaafia ni iru asiko bayi.
O kesi awọn ọdọ paapa awọn to lewaju iwọde ENDSARS bi Folarin Falana,Falz, Debo Adebayo Mr Macaroni, ati Seun Kuti lati darapọ mọ oun nibi iwọde alaafia kan.
Bẹẹ naa ni Gomina SanwoOlu sọ pe ko si awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okere kankan ti yoo ba awọn mu idagbasoke ba ilu Eko.
Tori naa o wa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati gbaruku ti ijọba lati bori iṣẹlẹ aburu yi.