Woman killed in front of Deeper Life Oka: Ọmọ olóògbé ní aago márùn-ún sí mẹ́fà àárọ̀ ọjọ́ ìsinmi ní màmá máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láti tún ibẹ̀ ṣe ṣaájú ìsìn

Awọn mọlẹbi mama Veronica Dare ti awọn eeyan kan pa lasiko to n gba ilẹ ile ijọsin Deeper Life nilu Iwaro Oka Akoko nipinlẹ Ondo, ti figbeta.

Awọn mọlẹbi naa ti pariwo pe awọn eeyan to da ẹmi mama ẹni ọdun mejidinlọgọrin naa legbodo, lo sisẹ ibi ọhun lati fi iya awọn se etutu ọla.

Ọmọ Oloogbe, Boniface sọ fawọn akọroyin pe wọn ti yọ ọfun atawọn ẹya ara mama awọn lọ, lẹyin ti wọn pa tan.

Boniface ni asa mama awọn ni lati maa ji lọ tun ile ijọsin naa se, ko le wa ni imọtoto, ki isin ọjọ isinmi to bẹrẹ.

"O si seese ko jẹ pe awọn olubi ẹda yii lo ti sakiyesi pe mama wa maa n ji lọ tun ile ijọsin se ni aago marun abọ si aago mẹfa owurọ ni gbogbo ọjọ Aiku.

Awọn eeyan yii si lo daju pe wọn tọpasẹ mama lọ si sọọsi lati sisẹ ibi naa.

Inu ewu la wa ni agbegbe yii nitori a ko mọ ẹni to kan, o si yẹ ki awọn agbofinro dide lati tete se awari awọn osika ẹda to wa nidi ipaniyan naa.

A si n rọ ijọba atawọn agbofinro lati se awari awọn eeyan naa, ki wọn le finmu ko ata ofin."

Àwọn àjòjì ṣá obìnrin tó ń lọ gbálẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Deeper Life pa, ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ara rẹ̀

Bi wọn ba n gbadura pe iroyin aburu ko ni kan wa, kii ṣe adura kekere o amọ iroyin aburu ti kan ijọ yii ati idile Veronica Dare.

Lowurọ kutu ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgọta oṣu kọkanla ọdun 2021 ni awọn oniṣẹ aburu ti ẹnikẹni ko mọ lọ ṣa arabinrin yii pa niwaju ṣọọṣi to ti n jọsin ni ijọba ibilẹ Akoko Southwest, Ondo.

A gbọ pe gbogbo ọjọ isinmi ni Arabinrin Veronica Omode maa n ji lọ gba ilẹ inu ijọ Deeper Life Bible Church to wa lẹyin ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti Owalusin, Oka nipinlẹ Ondo.

Ni nkan bii ago marun abọ owurọ oni ni eeyan kan to n gbe ni adugo naa sọ fun BBC pe loju ọna rẹ to n lọ si ile ijọsin lati lọ tọju rẹ ni wọn pa a.

Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo kan ti ọmọ Arabinrin naa ti sọrọ pe aarọ ọjọ Aiku ni iya oun jade kuro nile lati lọ gba ṣọọṣi.

"Bii ago marun owurọ kọja ni wọn kuro nile latu lọ gba ṣọọṣi. Wọn pe mi naa ni nile pe wọn pa wọn si ẹgbẹ ṣọọṣi. O dun mi gidi gan".

Ọ sọ fun awọn oniroyin pe ẹgbẹ ile ẹkọ naa ni ile ti iya oun n gbe wa. O ni kia ti awọn ri ohun to ṣẹlẹ ni awọn pe Ọlọpaa ti wọn si ti wa sibẹ.

O ni awọn rii pe wọn ti ge lara ọrun mama oun kuro.

Bakan naa ni iroyin ni wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igboku pamọ si.

Ninu fidio ti awọn araalu fi ṣọwọ si BBC lati gbọ ti awọn ara adugbo n sọkun kikoro ti wọn n pariwo pe iya Pasitọ ni Arabinrin naa pe ilẹ si lo wa gba ni ṣọọṣi naa to wa lẹyin ileewe.

Bakan naa wọn ni ko si eeyan to n gbe adugbo naa, kiki ile ẹkọ alakọbẹrẹ yẹn ati ile ijọsin lo wa ni agbegbe naa.

Titi di akoko ti a ko iroyin yii jọ, ko tii si ẹni to mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ amọ nipa biboju wo ara rẹ ninu agbara ẹjẹ, o jọ pe wọn ṣa a ni nkan lọrun ni.