Baba Suwe: Wo ohun mẹ́jọ tó ṣe kókó nípa olóògbé Babatunde Omidina

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ní kété ti wọn kéde iku ogbontarigi adẹrinposonu nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe ni ọpọ eeyan ti n bèèrè pé awọn fẹ mọ sii nipa oloogbe naa.

Ọjọ Aje, ọjọ Kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021 ni Baba Suwe, tii se gbajumọ osere tiata ati adẹrinposonu, dagbere faye lasiko aisan ọlọjọ pipẹ.

Ọdun mẹtalelọgọta ni oloogbe agba osere naa lo loke eepẹ, ko to tẹri gbasọ.

Ọjọbọ, ọjọ Kẹẹdọgbọn osu Kọkanla ọdun 2021 ni Baba Suwe si wọ kaa ilẹ sun nilana ẹsin Islam nile rẹ to wa ni opopona Oluwatimiro, ibudokọ Ewu-Elepe, ni opopona Ijede nilu Ikorodu

Bi itan aye oloogbe Babatunde Omidina si se lọ ree:

A bi Babatunde Omidina ni ọjọ kejilelogun, osu kẹjọ, ọdun 1958 ni Ijoba ibile Ikorordu nipinlẹ Eko ni guusu Naijiria.

Baba Suwe dagba ni agbegbe Lagos Island nipinle Eko.

O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Jamaitu Islamial ati Children Boarding School ni Osogbo ni ipinlẹ Osun.

Lẹyin naa lo lọ sile ẹkọ girama ti Adekanbi Commercial High School ni Mile 12 nipinle Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileẹkọ Ifeoluwa Grammar School ni Osogbo nipinle Osun lo ti pada se idanwo asekagba oniwe mẹwaa rẹ

Babatunde Omidina bẹrẹ isẹ ere itage ni sise lọdun 1971 ko to di gbajugbaja pẹlu ere sinima agbelewo Omolasan.

Awon ere mii to gbe Baba Suwebatu jade sita ni Iru Esin ti Olaiya Igwe, Ebun Oloyede se ni 1997, Baba Jayejaye ti oun ati Funke ?Akindele jọ se papọ pẹlu Femi Adebayo

Lodun 2011 ni ajọ NDLEA to n gbogun ti asilo oogun oloro fẹsun kan Baba Suwe ni eyi ti ile ejọ giga ipinlẹ Eko pada danu pe ibanilorukọjẹ ni ẹsun naa.

Oloogbe Bamidele Aturu to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan lo soju fun Baba Suwe ninu igbejọ naa.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà ń ṣèdárò Baba Suwe tó jáde láyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ni gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Babatunde Omidina, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Suwe ti jade laye.

Ọmọ oloogbe ọhun, Adesola Morenikeji Omidina lo kede iku agba oṣere naa loju opo Instagram rẹ.

Morenikeji ni "Eyii ni lati kede pe baba mi, ọgbẹni Babatunde Omidina ti jade laye... ki Ọlọrun ti ẹmi rẹ si afẹfẹ rere."

Gẹgẹ bii ọpọ awọn ololufẹ rẹ sẹ mọ, Baba Suwe ti fi awọn akoko kan ṣaisan, eyii ti mu ki awọn eeyan kan maa gbe iroyin ofege nipa iku rẹ ṣaaju.

Lara awọn to ṣeranwọ owo fun oloogbe naa lasiko naa ni wolii Esther Ajayi.

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 1958, eyiun ọdun mẹtalelọgọta sẹyin, ni wọn bi baba Suwe ni Lagos Island, ni ipinlẹ Eko.

Lẹyin ti iroyin iku Baba Suwe lu jade lori ayelujara, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ.

Lara awọn agba oṣere to ti ṣedaro iku Baba Suwe ni arabinrin Modupe Johnson, ti ọpọ eeyan mọ si Fali Werepe.

Yatọ si Fali Werepe, awọn oṣere mii bii Yomi Fabiyi naa ti n kẹdun iku Baba Suwe.

Adura wa ni pe ki Eledua tẹ ẹ si afẹfẹ rere.