You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Anambra election and police security: Ọ̀lọ́pàá 34,587 níjọba àpapọ̀ ń rán lọ Anambra láti kojú agbébọn tó bá gbémú lásìkò ìbò gómìnà
Oṣu kọkanla ọdun 2021 ni eto idibo sipo gomina nipinlẹ Anambra yoo waye, bẹẹni kukukẹkẹ awọn ikọlu agbebọn ko yee waye nibẹ eleyi to n mu ki ọpọlọpọ maa bere pe ṣe ibo yoo lee waye nipinlẹ Anambra?
Nibayii, ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti ko ọlọpaa ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn o le ọrinlelẹẹdẹgbẹta ati meje (34,587) lọ si ipinlẹ Anambra bayii.
Lasiko ipade agbeyẹwo ibi tọrọ abo de duro eleyi tawọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa maa n ṣe loorekoore, eyi to waye lolu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abuja lọjọbọ ni Ọga ọlọpaa Alkali Baba ti paṣẹ ki wọn ko awọn ọlọpaa naa gba Anambra lọ.
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí àwọn agbésùmọ̀mí àti agbébọn tó ń pẹ̀ka bí ìrókò-Afenifere
- Iyorchia Ayu di alága tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
- A pinu láti sinmi díẹ̀ lẹ́yìn ìgbeyàwó ká tó bímọ àmọ́ ó yíwọ́ - Wumi Toriola
O ni igbesẹ naa ṣe pataki lẹyin ti wọn ṣe ọfintoto awọn wahala to lee fẹ bomipana alaafia lasiko idibo sipo gomina to n bọ lọna nipinlẹ Anambra.
Bakan naa lo tun paṣẹ ki wọn ko baluu ọlọpaa mẹta dani bi wọn ba nlọ ki wọn si ko awọn irinṣẹ ọlọpaa oju omi, ọlọpaa to n fẹranko ṣiṣẹ atawọn ẹka miran pẹlu dani lọ koju awọn agbebọn tabi janduku to ba fẹ gbemu lasiko idibo naa.
Awọn ọlọpaa kogberegbe MOPOL, awọn ti ikọ to n koju ado oloro awsn to n koju agbesunmọmi ati awsn ikọ miran nileeṣẹ ọlọpaa n ko lọ sipinlẹ Anambra.
Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Frank Mba fi sita fi kun un pe gbogbo awọn ọga agba ẹlẹkunjẹkun, ati kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ gbogbo lorilẹede Naijiria ni wọn ti ke si pe ki wọn tete lo tubọ so okun abo ko le daindain lawọn ẹka ti wọn fiwọn jẹ le lori.