You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP Chairmanship race: Iyorchia Ayu di alága tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
Aarẹ ile asofin agba nigba kan ri, Sẹnetọ Iyorchia Ayu ni wọn yan bayii gẹgẹ bi alaga tuntun fun apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP bayii.
Fun asiko diẹ ni ariyanjiyan ti n waye lori ta gan ni yoo dari ẹgbẹ oṣelu PDP wọ inu saa idibo loriṣiriṣi to n bọ lọna ti yoo si ṣide fun eto idibo apapọ ọdun 2023.
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- A pinu láti sinmi díẹ̀ lẹ́yìn ìgbeyàwó ká tó bímọ àmọ́ ó yíwọ́ - Wumi Toriola
- Wo bí àṣà ìbálé lálẹ́ ìgbeyàwó ṣe ń dọdẹ àwọn obìnrin òde òní kiri
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
Orukọ Sẹnetọ Ayu jade lẹyin ipade ọlọpọ wakati laarin awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ oṣelu naa lẹkun ariwa orilẹede Naijiria, eleyi to waye nile ijọba ipinlẹ Bauchi to wa nilu Abuja.
Igbimọ iṣakoso apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti pin ipo alaga ẹgbẹ oṣelu naa fun iha ariwa.