You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wumi Toriola: Mo gbé ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ láti lóyún lẹ́yìn ìgbeyàwó àmọ́ pàbó ló jásí kí Ọlọ́run tó síjú àànú wò mí
Igbagbọ ọpọ ọmọ Yoruba ni pe Ọlọrun lo n se ọmọ, kii se eeyan, agbara iloyun ati ọmọ bibi si wa lọwọ Eledumare ọba to le se ohun gbogbo.
Igbagbọ awọn eeyan yii si lo wa si imusẹ ninu aye gbajugbaja osere tiata lobinrin kan, Wumi Toriola.
Bi o tilẹ jẹ pe Wumi se igbeyawo alarinrin, to si pẹ diẹ ko to fi inu soyun, ọpọ eeyan lo n lero pe o kan wu bẹẹ ni lai mọ pe isoro nla ni oserebinrin naa la kọja.
Toriola, ẹni to bọ soju opo Instagram rẹ lati kede ayẹyẹ ọdun keji ti ọmọ rẹ de ile aye, wa lo anfaani ọjọ ibi naa lati kede fun araye nipa ọpọ isoro to la kọja, ko to di ọlọmọ nile aye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- Odunlade, a fún ọ lọ́jọ́ méje, yọ sinimá tó ń fi ẹlẹ́hàá ṣe yẹ̀yẹ́ kúró lórí ayélujára - Ẹgbẹ́ THURIST
- Àgùnbánirọ̀ yóò kojú Boko Haram, agbébọn pẹ̀lú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ológun - Fayemi
- Ilé aṣòfin Kwara dá sí ọ̀rọ̀ iléẹ̀kọ́ Kéú tó fìyà jẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Egúngún fi àdá gba ₦370,000, ọ̀rọ̀ di wàhálà l‘Ondo
- Kò sí iṣẹ́ fún òṣìṣẹ́ ọba tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára títí December 1 - Ìjọba àpapọ̀
- Ìgbésẹ̀ tà ń gbé rèé lórí ìlera Sunday Igboho àti ìtúsílẹ̀ rẹ̀ - Ilana Ọmọ Oodua
- Ẹ wo ọmọbabinrin ilẹ̀ Japan to sọ ipò iyebíye ti owó rẹ̀ tó $1.3m nù nítorí olólùfẹ́
- "Bí ń kò sún mọ́ Sunday Igboho, ogun abẹ́lé kò bá ti wáyé ní Nàíjíríà"
- Aṣòfin méjì wọ gàù lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ agbébọn
- "Ẹ tètè gbé Sunday Igboho lọ fún ìtọ̀jú lókè òkun, kó tó pẹ́ jù"
Ninu alaye rẹ, Wumi ni lẹyin ayẹyẹ igbeyawo oun, oun ati ọkọ oun pinnu lati sinmi diẹ naa, kawọn to bẹrẹ owo ọmọ bibi.
Amọ nigba ti akoko isismi wọn buse ni wọn ba ko mọ isẹ ọmọ bibi sugbọn gbogbo aisun tọkọtaya naa tọsan toru lo ja si pabo, ti oyun ko si duro rara.
"Laarin osu mẹfa akọkọ ta pinnu lati loyun ni a ko fi gbọ ko amọ n ko tiẹ mọ lọran kankan nigba naa.
Amọ nigba to di ọjọ kan, ni eeyan kan sọ fun mi pe se mo lero pe o rọrun lati finu soyun ni, sebi igbeyawo ni mo se yẹ, ki lo de ti n ko se tii loyun, to ba jẹ pe lootọ lo rọrun lati se bẹẹ."
Wumi ni igba yii gan ni oun to mọ ọrọ naa ni nnkan patak, ti oun si gba ile iwosan to wa fun oyun nini ati ọmọ bibi lọlati lọ se ayẹwo pẹlu ọkọ oun.
Amọ o ni dokita fidi rẹ mulẹ pe saka ni ara oun ati ọkọ oun da, ti ko si si nkankan to n se idiwọ fun awọn mejeeji lati finu se oyun.
"Amọ sibẹ n ko lyun lẹyin ayẹwo yii, ti mo si tun lọ sibi ti wọn yoo ti se iranwọ lati fi ẹrọ kan gbe atọ ọkọ mi sile ọmọ mi, ti oloyinbo n pe ni Intrauterine Insemination.
Ẹmeji ni wọn se nnkan yii fun mi, ti gbogbo rẹ si kuna, n ko gbọ pa, bẹẹ ni n ko gbọ ko.
Amọ nigba to ya Ọlọrun lo sisẹ iyanu rẹ, ti mo si loyun, eyi ti mo fi bi ọmọkunrin to pe ọdun meji yii."
Wumi Toriola wa gba awọn ololufẹ rẹ to n woju Ọlọrun ninu igbeyawo wọn nimọran pe kii se awọn nikan lo n la iru isoro naa kọja.
"Aimọye miliọnu obinrin lo n ba isoro airọmọbi yii finra, amọ mase ri ara rẹ bi ẹni ti ko le finu soyun laelae nitori isẹ iyanu rẹ sun mọ itosi."
O tun wa rọ iru awọn eeyan yii wipe ki wọn mase fi oogun wọn sere, ki wọn si maa lọ sile iwosan loore koore, bẹẹ ni ki wọn maa gbadura si Ọlọrun nitori Ọlọrun to ya Wumi Toriola lẹnu, yoo ya awọn naa lẹnu.