Yoruba Films: Ireoluwa ṣ'ọjọ́-ìbí, Mide àti ọkọ rẹ̀ lẹ̀pọ̀, Iyabo Ojo f'aṣọ ilẹ̀ Afirika dárà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ nii pẹ, ipade kii jinna. N jẹ ẹ mọ pe ọmọ ti Ọlọrun fi ta idile Toyin Abraham ati ọkọ rẹ lọrẹ ti ṣ'ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kan.

Eyi ni awọn ohun to ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere tiata lọsẹ yii.

Toyin Abraham

Bi ọmọde o ku, agba ni i da. Ire Oluwa, ọmọkunrin lanti-lanti ti Eleduwa fi jinki idile gbajugbaja osẹre, Toyin Abraham ati ọkọ rẹ, Kolawole Ajeyemi ti pe ọdun kan.

Ọjọ kẹtala oṣu kẹjọ ọdun 2020 yii naa ni Ire pe ọmọ ọdun kan loke eepẹ, eyi ti awọn obi rẹ fi n dupẹ lọwọ Eleduwa ti O da ọmọ naa si i.

Kolawole pẹlu aya rẹ Toyin lo fi aworan ọmọ naa sori oju opo Instagram wọn nibi ti wọn ti ọrọ iṣiti ati idupẹ lori ọjọ ibi Ire Oluwa.

Mide Martins

Mide Martins ati ọkọ rẹ, Afeez Owo lẹ pọ ninu sinima ti akori rẹ n jẹ ''SALAWA.''

Aworan Mide ati Afeez Owo lo han gbagada lori paali sinima ''SALAWA'' naa.

Sinima naa da lori ọmọbinrin kan, ''SALAWA'' to sọ ara rẹ nu, to gbagbe ile. Ẹkunrẹrẹ wa ninu sinima ọhun.

Wumi Toriola

Yoruba bọ, wọn ni bi ile da bi ko da, awọ ni ẹ wo. Eyi lo mu ki oṣere Wumi Toriola jawe s'obi ninu fọto to fi si oju opo Instagram rẹ.

Wumi ṣalaye pe o ṣe pataki fawọn ọdọmọbinrin lati ni aṣọ to juju n gbese eyi to yoo maa mu wọn ri bi ọmọ kekere ni gbogbo igba.

O fikun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti obinrin to ba ti n dagba ko le lanfaani lati di ọdọmọbinrin pada, o ni wiwọ aṣọ to ba igba mu lọna miiran ti obinrin fi le da bi ''ayọngẹ.''

Iyabo Ojo

Aṣa ilẹ Afirika ni Iyabo Ojo gbe larugẹ lọsẹ yii loju opo Instagram rẹ.

Niṣe ni gbajumọ oṣere Iyabo ko sinu aṣọ alaranbara to ni awọ dudu ati funfun ninu eyi to ti n ṣakọ ninu fọto to ya.

Oriṣii ara ni Iyabo da ninu aṣọ to wọ ọhun, bi o ṣe n yanu si atẹgun lo tun duro siwaju ile awo dami ẹnu kan to fi ya fọto.