You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Afenifere Vs Buhari: Ìsọwọ́ gba àkóso àwọn agbésùmọ̀mí ń pè fún ìgbésẹ̀ kíákíá
Ẹgbẹ to n ja fun itẹsiwaju awọn ọmọ ilẹ Yoruba, Afenifere ti kesi aarẹ orileede Naijiria lati wa wọrọkọ fi ṣada lori ipenija aabo to n ba ilẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Comrade Jaye Ajayi fi sita, o ni ijọba ni lati tete gbe igbesẹ to munadoko ki Naijiria ma baa tuka.
Ni paapa, Jaye sọ pe ọwọ tawọn agbesunmọmi ṣe n pẹka si lawọn ilu apa ariwa Naijiria ati bi awọn agbebọn ṣe n ṣoro ni ilẹ Igbo jẹ ohun to yẹ fun atunṣe kiakia.
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- A pinu láti sinmi díẹ̀ lẹ́yìn ìgbeyàwó ká tó bímọ àmọ́ ó yíwọ́ - Wumi Toriola
- Wo bí àṣà ìbálé lálẹ́ ìgbeyàwó ṣe ń dọdẹ àwọn obìnrin òde òní kiri
- Àgùnbánirọ̀ yóò kojú Boko Haram, agbébọn pẹ̀lú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ológun - Fayemi
Gẹgẹ bi o ti ṣe ṣalaye, o ni iwadii kan fi han pe awọn agbebọn yabo olu ileeṣẹ agọ ọlọpaa to wa ni
Umulokpa, ni ijọba ibilẹ Uzo-Uwani ni Enugu lọjọ Ẹti ti wọn si jin ọlọpaa kan gbe.
O ni eyi nikan kọ, wọn tun gbe awọn eeyan meje mii to wa ni ibudo ti wọn ti n kọ nipa ẹsin,St Albert the Great Institute of Philosophy, ni Kaduna lọjọ Aje.
O sọ pe awọn iṣẹlẹ yi jẹ itọka si ọwọja bi awọn agbebọn ṣe n ṣe ikọlu si awọn agọ ọlọpaa ati ibudo awọn ọmọ ologun ni Naijiria.
''Lọsẹ to kọja la gbọ pe awọn aṣẹku ọmọ ikọ Boko Haram n da ibuba silẹ lawọn abule kọọkan ni ilu Kuje ni Abuja to jẹ olu ilu Naijria''
''Koda alaga ijọba ibilẹ Shiroro ni ipinlẹ Niger Họnọrebu Suleimn Chukuba naa sọ pe awọn agbesunmọmi ti gba ibudo to fẹ ẹ to ẹẹdẹgbẹta ni agbegbe naa''
Yatọ si awọn akawe yi ti Afenifere sọ pe o to ki wọn wa nkan ṣe si, ẹgbẹ naa tẹsiwaju pe lawọn apa kan ilẹ kaarọ o jiire bi opopona Ibadan si Ijebu, apa kan Ondo,Ekiti,Ogun ati Osun,iwa ijinigbe ati adigunjale n waye
leralera.
''Iru nkan bayi tun ṣẹlẹ ni ipinlẹ Edo to fi mọ awọn ibomiran naa''
Ninu amọran wọn, afẹnifẹre ni ijọba aarẹ Muhammadu Buhari mọ́ gbogbo ipenija to n koju Naijiria bẹẹ si ni wọn mọ ọna abayọ.
Wọn ni idi ni pe Aarẹ fun ara rẹ nigba to n polongo ibo lọdun 2011 labẹ asia CPC ti sọ pe idasilẹ ọlọpaa abẹle jẹ ọna kan gbogi lati fi dẹkun ipenija aabo to n koju Naijira.
Lootọ ni aarẹ ko wọle ni ọdun 2011 ṣugbọn lati igba to ti wa lori oye,o ṣa ti yẹ ko wa nkan ṣe si ọrọ yi nipa lilo aba to da nigba to n polongo ibo.
Afẹnifẹre sọ pe asiko ka maa fẹsẹ wọle ko si mọ bi kii ṣe pe ki aarẹ wa wọrọkọ fi ṣada.
Ninu amọran ti wọn gba aarẹ ni pe ki:
- Ijọba jawọ ninu irori aye atijọ
- Ki wọn pese irinṣẹ ija fawọn agbofinro ati ọmọ ogun to fi mọ owo to jọju gẹgẹ bi moriya fun wọn
- Ki ijọba foju awọn janduku ti ọwọ ba tẹ wina ofin lai fọwọ bo ẹnikẹni mọra
- Fifun awọn Gomina ni agbara to yẹ lati le fi pese aabọ lagbegbe wọn nipa ọlọpaa ti wọn yoo le paṣẹ fun
- Pipe ipade awọn alẹnulọrọ ti ko ni yọ ẹya kankan silẹ da lori ipenija to wa nilẹ yi