School Kidnap in Nigeria: Wo iye ìgbà tí wọ́n ti jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Nàìjíiríà

Opọ̀ igba ni wọ́n ti ji akekọ́ọ́ gbe ni orilé-ede Naijiria.

Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau gbé lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé lọjọ Isegun

Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau ti tún ṣe òfin kóníléógbélé oní láyípo ni ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Jos, ìpínlẹ̀ Plateau.

Adari ìbánisọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ tó n lọ fún gómìnà ipínlẹ̀ Plateau, Simon Lalong, Makut Macham lo kéde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta l'Ọjọ́rú.

Òfin kóníléógbélé náà wáyé nítórí ìkólu tó ṣẹlẹ̀ ní Yelwa Zangam, abúlé kan ni ẹkùn Zangam ni ìpínlẹ̀ Plateau.

Gẹ́gẹ́ bí Gómínà ṣe sọ òfin kóníléógbélé náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ òni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kẹjọ, ọdún yìí títí di ìgbà tí ẹnikẹ́ni ko tíì mọ̀.

"Igbésẹ̀ oníwàrànṣesà yìí pọndandan nítorí wàhálà tó n dúkoko mọ ìwàláàyè àwọn ara ìlú ni ìjọba ìbílẹ̀, ó sì pọndandan kí a mójútó kí nǹkan to bàjẹ́ jìnà."

" Èyí yóò ràn àwọn agbófinro lọ́wọ́ pẹ̀lú láti ṣe iṣẹ́ wọn bi ó ti tọ́ àti bi ó ti yẹ, àti láti ṣe àwárí àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú náà."

"Gómínà tí wá rọ àwọn ará ìlú pàápàá jùlọ àwọn ará àríwà ni Jos láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba nípa tílèlé òfin kóníléógbélé náà ti yóò bẹ̀rl ni aago mẹ́rin ìrọ̀lé òní."

Ìjọba ti pọn ni dandan fun awọn agbófinro pe kí wọ́n fi ọwọ́ òfin mú ẹnikẹni tí ó ba ki etí ọ̀gbọ̀in si àṣẹ náà."

Gómìnà Lalong tun fi kun pé, òfin kónílé o gbélé alaago mẹ́fà alẹ́ sí ti ìdájí náà wà ni ìhà Gúúsù Jos náà títí di àsìkò ti wan kò mtí mọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn tó n ṣe iṣẹ́ bi nọ́ọ̀sì, dókítà, oníròyìn, àwọn panápaná àti awọn eletò ààbò nikan ni ofin fi aaye gbà láti jáde.

Sùgbọ́n kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí rii dájú pé, wọ́n mú ìwé ìdánimọ̀ wọn dání.

" Lẹ́ẹ̀kan si gómìnà bá àwọn to pàdánù ẹbi wọn láti fi ọ̀kan bálaẹ̀ kí wọ́n sì gba ìjọba láàyè láti mójú tó ọ̀rọ̀ náà kí àwọn oníṣẹ́ ibi náà má baa fi ìyà jẹwọ́n gbé."

Jos killings: Àwọn jàndùkú agbébọn tún yìnbọn pa èèyàn tó lé ní 30 nílùú Jos

Iroyin yajoyayo to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Plateau sọ pe awọn janduku agbebọn tun ti fi ẹmi eeyanto le lọgbọn ṣofo lagbegbe Yelwan Zangam ni ijọba ibilẹ ariwa ilu Jos.

Ti ẹ ko ba gbagbe, bi ọsẹ meji sẹyin lawọn agbebọn ṣekupa arinrinajo mẹẹdọgbọn to n lọ si Ondo niluu Jos.

Amọ iroyin sọ pe bi ago mẹsan an ku iṣẹju mẹẹdogun ni alẹ ọjọ Iṣẹgun lawọn janduku yii yabo awujọ Yelwa Zangam nibi ti wọn ṣọṣẹ di oru mọju Ọjọru.

Ọba awọn ẹya Anaguta to wa lagbegbe tawọn agbebọn kọlu yii, Ujah Johnson Jauro fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akọroyin.

Kọunsilọ wọọdu Ahwol lawujọ naa, Yusuf Ali ṣalaye pe awọn janduku naa dana sun awọn kan laaye.

Aṣofin ni afara to so awujọ naa pọ mọ awọn agbegbe mii lawọn janduku ọhun kọkọ bajẹ ko le nira fawọn ẹṣọ eleto abo lati wa doola awọn eeyan.

Kọunsilọ naa ni bawọn janduku yii ti de awujọ naa ni wọn dabọn bolẹ, bakan naa lo sọ pe wọn tun dana sun ọpọ ile.

O ni ọpọ oku awọn eeyan ni wọn ti ko lọ si ile igboku si nigba ti ọpọ eeyan si fara pa yanayana.

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.