Niger kidnap: Mẹ́fà nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Islamiyya Tegina ti kú sí àkàtà àwọn ajínigbé

Mẹfa ninu mẹrindinlogoje akẹkọọ ile ẹkọ Salihu Tanko Islamiyya tawọn janduku ajinigbe pawo jigbe niluu Tegina nipinlẹ Niger ti ku si akata awọn ajinigbe.

Ọga ile ẹkọ naa, Abubakar Alhassan, ṣalaye pe lana ọjọ Iṣẹgun lawọn janduku ọhun sọrọ iku awọn akẹkọọ naa foun lori foonu.

Awọn ajinigbe ni aisan ajeji kan lo ṣekupa awọn ọmọ naa ninu igbo ti wọn wa.

Awọn janduku ajinigbe yii si duro lori ẹsẹ wọn pe igba miliọnu naira lowo itusilẹ tawọn n beere fun lawọn si maa gba, bo tilẹ jẹ pe mẹfa ti ku ninu awọn akẹkọọ naa bayii.

Abubakar Adam, ọkan lara awọn obi to ni ọmọ mẹfa lakata awọn ajinigbe naa fidi ọrọ ọhun mulẹ.

Iroyin kan tiẹ sọ pe awọn obi pakiti mọri wa aadọta miliọnu san fawọn janduku ọhun, ṣugbọn wọn ni igba miliọnu gbọdọ pe.

Awọn eeyan awujọ Alawa ni ijọba ibilẹ Shiroro nipinlẹ Niger State ti sọ tẹlẹ pe awọn ri awọn akẹkọọ ọhun nibi ti wọn ti n gbe wọn lọ lori ọkada.

Amọ, ko si ẹni to tii gburo wọn di akoko yii.

Ẹwẹ, kọmiṣọnaa ọlọpaa tuntun nipinlẹ Niger, Bala Kuryas ti sọ pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo wa awọn ọmọ ri laipẹ.

Iṣẹlẹ ijinigbe ti ṣẹlẹ lera lera ni ipinlẹ Niger, awọn akẹkọọ lo si pọju ninu awọn ti wọn jigbe.