Ǹkan mọ́kànlá tí o ni láti mọ̀ nípa Sẹnatọ Biyi Durojaiye tó d'Ólògbé

Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin nígbà kan rí Sẹ́nátọ̀ Biyi Durojaiye kú ni òwúrọ̀ ọjọ́ Iṣẹgun ní ìlu'Eko ni ẹni ọdun méjìdínláàdọ́rùn.

Ìròyìn sọ pé Durojaiye ku sí ilé ìwòsàn lásìkò tó n gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Òun ni alága àjọ NCC nígbà kan rí, tó tún jẹ́ olóyè ni NADECO.

Àwọn nǹka ti ó yẹ kí o mọ̀ nípa sẹ́nátọ̀ Biyi Durojaiye

A bí sẹ́nátọ̀ Biyi Durojaiye ni inú oṣù kejì ọdún 1933

Durojaiye pari ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé ni London àti ìmọ̀ LLB ni London Bákan náà.

Wọ́n pèé sínú ẹgba àwọn agbẹjọ́rò ni ọdun 1979 ti ni ilé ẹja tto ga jùlọ ni Nàìjíríà

Ó ṣiṣẹ́ ìjọba fún ọdún márundinlógójì t fi mọ́ ọdún méjìdílọ́gbọ̀n tó lò gẹ́gẹ́ bi adarí àgbà ní ilé ìfówópàmọ́ Nàìjíríà (CBN).

Bákan náà ló ṣiṣẹ́ ni àjọ IMF àti ẹka àjọ tó n kówó ìlú pamọ́ ni ilẹ̀ Amẹrika àti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ni ọdun 1964 àti 1982.

Wọ́n dìbò yan Durojaiye silé ìgbìmọ̀ asofin lọdun 1988 si 1989.

Lọ́dún 1992 ó díje dupò àa[rẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsía ẹgbẹ́ òṣèlú SDP tí M.K.O Abiola sì fi ẹ̀yìn rl janlẹ̀.

Nínú oṣù kejìlá ọdún 1996, ìjọba ológun Sanni Abacha gbe tí wọ́n sì ti mọ́lé fún ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ.

Ó di ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àgbà ni ọdún 1999-2003.

Nínú oṣù kejìlá, ọdún 2002, o faramọ́ pé ki wọ́n máa ju ẹnikẹ́ni tó bá ṣe màgòmágó ìdìbò sí ẹ̀wọ̀n.

Olóògbé Durojaiye padánù ìyàwó rẹ̀ Florence Olufunso Adejoke ni ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹfà, ọdún 2009 ní ẹni ọdún méjiléláàdọ́rin, èyí wáyé lẹ́yìn oṣù méjì ti wọ́n ṣe àyájọ́ àádọ́ta ọdún ti wọ́n ṣe ìgbéyàwó