Secondus visits Obasanjo: Nítorí wàhálà tó ń wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú rẹ̀, Uche Secondus, alága PDP mórílè ilé ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, dailytrust
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọọba Uche Secondus ti gunlẹ si ilu Abẹokuta nile aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ.
Ni nnkan bii agogo mejila ni Secondus gunlẹ, ti ọpọ si n woye pe abẹwo alaga apapọ PDP naa ko yẹ lori wahala to n lu agogo jo laarin ẹgbẹ oṣelu naa bayii.
Lọwọ yii, Secondus n ja fitafita lati di ipo rẹ mu gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu naa lẹyin ti awọn eekan kan laarin ẹgbẹ oṣelu naa n sọ fun un pe ile to lọ, ko fi ipo silẹ.
- Ara mi bó fẹ́lẹ-fẹ̀lẹ lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ immigration lù mí mọ́ ọfíìsì mi - Alaga Ibadan North
- Bí àwọn ọmọ Yoruba bá ní ìbọn láti dáàbò bo ara wọn báyìí kò burú - Afenifere, YCE
- Ṣé mo jọ ẹni tó gba Benin Republic sá kúrò ní Nàìjríà ni? Lai Mohammed fèsí sí ìróyín pé Ó yọ́ kẹ́lẹ́ kúrò ní Nàìjíríà
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
Gbogbo akitiyan awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa lati bomi pa ina wahala naa ni ko tii ba ọwọ rere jade.
Ohun ti o han si gbogbo eniyan ni pe Oloye Ọbasanjọ ti fa kaadi ọmọ ẹgbẹ rẹ ya to si ti juwọ si ẹgbẹ oṣelu PDP, amọṣa gẹgẹ bi ẹni to fi ọdun mẹjọ jẹ aarẹ alagbada labẹ aburada ẹgbẹ oṣelu naa, ọpọ onwoye lo n woo pe ko ni ṣai ni ipa to loorin laarin awọn eekan ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa.









