Sunday Igboho: YCE rọ àwọn ọ̀dọ́ láti ṣọ́ra, ki wọ́n má baà di ẹran àmúso lọ́dọ̀ ìjọba bíí Igboho

Ẹgbẹ awọn agbaagba nilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders(YCE) ni awọn n ṣiṣẹ labẹlẹ lati ri pe Oloye Sunday Adeyemo (Igboho) gba ominira lọgba ẹwọn to wa ni Cotonou lorilẹede Benin.

Akọwe agba ẹgbẹ YCE, Ọmọwe Kunle Olajide ṣalaye pe ọdọ Naijiria ko ni ireti mọ ninu orilẹede wọn nitori ko si ohun iwuri kankan fun wọn.

''Awọn ọdọ ko le fi ara da ọpọ nkan ti awọn agbalagba le gba mọ ra tori wọn maa n ro pe ijọba n fi akoko wọn ṣofo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ YCE ko lodi si ohun tawọn ọdọ Yoruba n ṣe ṣugbọn a kan n kilọ fun wọn pe ki wọn rọra ṣe ni.

A ko fẹ ki ijọba sọ wọn di ẹran amoso tori ijọba lagbara to pọ, ohun to n ṣẹlẹ gan an niyii pẹlu ọrọ Igboho.

Gbogbo agbara ti a ni, la n lo lati ri pe Igboho kuro ni atimọle to wa lorilẹede Benin Republic,'' Ọmọwe Olaide ṣalaye.

Ninu atẹjade mii ti akọwe ẹgbẹ YCE, ẹka ipinlẹ Ekiti, alagba Niyi Ajibulu fi sita, ẹgbẹ naa bu ẹnu atẹ lu eto abo to mẹhẹ kaakiri orilẹede Naijiria bayii.

Pa Ajibulu sọ ninu atẹjade naa pe ọrọ eto to mẹhẹ buru debi pe ẹru n ba awọn araalu lati rinrin ajo lati ibi kan lọ si ibomiran mọ.

''Eleyii buru pupọ, ko si gbọdọ tẹsiwaju, awọn Fulani darandaran, atawọn janduku ajinigbe lo yẹ ki ijọba wa nkan ṣe si ọrọ wọn ni kiakia.

Ẹgbẹ YCE gbagbọ pe orilẹede Naijiria wa fun gbogbo eeyan lai fi ti ẹya tabi ẹsin ṣe.

Ko si ẹni ti ko mọ awa Yoruba gẹgẹ bi ẹya to ni akinkanju, amọ iwa ẹlẹyamẹya ati siṣe egbe lẹyin ẹnikan ko dara.

Ko si idi kan ti o le mu ki ẹnikẹni fiya jẹ tabi ṣe inunibini si ọmọ Yoruba kankan.

Iyẹn lo jẹ ki ẹgbẹ YCE ke pe gbogbo ọmọ Yoruba lati fọwọ sowọ pọ, ki wọn si fẹnu ko pẹlu gbogbo nkan to n ṣẹlẹ lasiko yii lorilẹede Naijiria.

Ẹgbẹ YCE tun fi asiko yii kepe ijọba apapọ pe ko faye gba ijọba awarawa ni tootọọ ati agbekalẹ iwe ofin tuntun yatọ si ti ọdun 1999,'' Pa Ajibulu lo sọ bẹẹ.