Bola Tinubu: APC Eko ní Tinubu ló sọ Bode George di èèyàn lágbo òsèlú àmọ́ ògo rẹ̀ ti ń lọ sílẹ̀

Sáájú ìdìbò ọdún 2023 ní Nàíjírà àti ìpinu Asíwáju Bola Ahmed Tinubu láti di ààrẹ, oníruurú ọ̀rọ̀ ló n tàn ka lórílẹ̀-èdè Naàìjíríà.

Lára rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ti ìgbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) tẹ́lẹ̀ rí, Olabode George sọ pé, Ahmed Tinubu ko yẹ lẹni ti ó yẹ kí ó jẹ ààrẹ lọ́dún 2023.

Bode George fi kun pé, gbogbo ẹni to bá sì rò pé Tinubu ló tọ́ sí láti di ààrẹ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ nílò àyẹ̀wò nílé ìwòsàn.

Bákan náà ló sọ pé láàrín ọdún mẹ́jọ tí Tinubu fi jẹ gómínà ìpínlẹ̀ Eko gbogbo àlùmọ́nì ìpínlẹ náà lo ṣe básubàsu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Èyí lo wá mú kí àwọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ nilẹ oruba ati èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) fi n sọ òkò ọ̀rọ̀ padà sí Olabode George.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alága ẹgbẹ́ Yorùbá Welfare Group (YWG) Alhaji Abdulkareem Adegoke Alawuje ṣàlàyé pé, ìjà ìlàra ni Bode George ń jà àti pé ìjà ìlàra kìí tán bọ̀rọ̀.

Adegoke ni, gbogbo àwọn ìpìlẹ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Eko lónìí, Tinubu ló ṣe àgbékalẹ wọn, nítori náà, Bode George ko rì nǹkan sọ lórí pe Tinubu ṣe àlùmọ́nì ìpínlẹ̀ Eko básubàsù.

"Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Tinubu ko fi gba owó láti ọdọ̀ ìjọba àpapọ̀ síbẹ̀ , ètò ọ̀rọ̀ ajé Eko sì n ru gọbọi síí ni"

Bola Ahmed Tinubu ni olórí tí gbogbo ọmọ ilẹ̀ káàrọ̀-òò-jííre nílò ni àsìkò yìí, kíló de ti Yorùbá náà ló tún fa ọmọ Yorùbá sẹ́yìn.

Adegoke fi kún pé tí Bode George bá fẹ́ kúrò ní Nàìjíríà, kò ṣe nǹkankan fún ẹnikẹni nítorí kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, ẹrú ló rà wọ́n wá, orúkọ ẹru tó ra àwọn baba ńla bàbá rẹ̀ lo ń jẹ George.

Ó ni kìí ṣe òní ni Bode George ti máa n sọ ọ̀rọ̀ yìí, kò sì ni turu kankan lára ẹnikẹni nítorí pé, agbegbe Ìjọrá ni wọn kó awọn iran rẹ to jẹ ẹru si lásìkò owò ẹrú, ó sì wà lára àwọn ti kò mọ orísun wọn mọ́.

"Adegoke ní gẹ́gẹ́ bi ọmọ Nàìjíríà àti ọmọ Yorùbá, kò sí nǹkan tí ó le ṣẹ̀lẹ̀ ní Nàìjíríà, tí mo fi le ròó pé mọ̀ fẹ́ fi orílẹ̀-èdè mí sílẹ̀

"Gẹ́gẹ́ bi ẹni tó mọ pé wọ́n ra àwọn bàbá àwọn wá ni, kò ni niwọ́n lára láti padà sí ọ̀dọ́ àwọn tó rà wọ́n tàbi ibi ti wọ́n ti rà wọ́n kiri."

"Àwá sì le júwe ibi ti wọ́n ti rà wọ́n pẹ̀lú agádagodo lẹnu wọ́n" Láti ìgbà tí Bode George tí n ṣe òṣèlú kò sí ẹni tó ri ipa ire kan ti o se nilẹ Yorùba, ní Eko tabi ni orílẹ̀-edè Nàìjíríà."

" Ṣebí Bode George naa ti jẹ Gómìnà rí, kí lo ṣe lásìkò rẹ̀, kò sí ipa kankan ti wọ́n ni."

APC Eko ní ilara lo n yọ Bode George lẹnu, Tinubu lo si sọ di eeyan lagbo oselu:

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, akọ̀wé ipòlongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Eko, Joe Igbokwe ṣàlàyé pé ìlàra ni kò jẹ́ kí Olabode George gbádun nítori pé o kàn ń ṣe inúnibini sí àṣeyọri Bola Ahmed Tinubu ni Nàìjíríà ni.

Igbokwe to tẹpẹlẹ mọ pé, àṣeyọri Tinubu kò dúró ni ìpínlẹ̀ Eko nìkàn, bákan náà lo ni àwọn tó ti sọ di ènìyàn ńla láwùjọ, èyí ti òun gan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ti Tinubu sọ di èyàn.

Igbokwe ni o ti dandan tí ènìyàn bá jẹ ìlúmọ̀ọ̀ká, ọ̀pọ̀ ni yóò ma sọ̀rọ̀ rẹ̀, 'tí ènìyàn kan ba n lọ sókè, tí ẹlòmíràn si ń lọ sílẹ̀, ẹni tó n lọ sílẹ̀ yẹn yóò maa ba ẹni tó wà lóke jẹ́ ni.

"Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Bode George ṣe rí, Bode George ti tán, ó sì ń wá ẹni kúnra nítorí ètò òṣèlú rẹ̀ ti tán."

Ara àwọn alátìlẹyìn Tinubu láti di ààrẹ kò yá, wọ́n nílò àyẹ̀wò ọpọlọ - Bode George

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, agba ọjẹ kan ninu ẹgbẹ oselu PDP, Oloye Olabode George ti sọrọ soke lori erongba asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Tinubu lati du ipo aarẹ.

George fi ero rẹ lori erongba Tinubu lati du ipo aarẹ han lasiko to n kopa lori eto ori tẹlifisan kan nileesẹ Arise TV lọjọru.

Lero ti asaaju ẹgbẹ PDP naa, ara gbogbo awọn eeyan to n sugba Tinubu lati di aarẹ lọdun 2023 ni ara wọn ko ya, wọn si nilo ayẹwo ọpọlọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọmọ igbimọ majẹobajẹ fẹgbẹ oselu PDP naa ni oun yoo kede pe oun kii se ọmọ Naijiria mọ, ti Tinubu ba fi di aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Bẹẹ ba gbagbe, asaaju ẹgbẹ oselu APC kan, Adeseye Ogunlewe lo ti kọkọ kede pe Tinubu ni oludije to dantọ julọ lati dari Naijiria lọdun 2023.

Nigba to n fesi si ọrọ naa siwaju, George ni se ni oun bẹrẹ si ronu nigba ti oun gbọ ọrọ Ogunlewe naa nitori ọkunrin naa ti kọkọ sọrọ saaju lati tabuku Tinubu, to si wa ni akọsilẹ.

"Ki lo de tawọn eeyan kii le duro lori ọrọ ti wọn ba sọ gan? Ki lo de ti wọn n jo bi eleegun kiri laarin ọja?

Ta ba se agbeyẹwo ọdun mẹjọ ti Tinubu lo bii gomina nipinlẹ Eko, bawo la ti se idajọ rẹ si?

Mo setan lati ba Ogunlewe se ariyanjiyan nipa Tinubu nibi kibi, koda, ko baa jẹ ni itẹ oku ni aago mẹta oru, ọrọkọrọ lo n sọ lẹnu.

Koda, maa se ohun gbogbo to ba yẹ lati kede pe n ko kii se ọmọ orilẹede yi mọ ti Tinubu ba fi di aarẹ."

Bode George, ẹni to ni ọmọ ipinlẹ Eko ni oun, oun si mọ awọn nnkan ti Tinubu se, wa fi ọwọ sọya pe ko yẹ bii aarẹ rara, ti awọn gomina miran to dari ipnilẹ Eko si kaato julọ.