You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lizzy Anjorin: N kò fẹ́ Aláàfin o, àmọ́ ó ní ń kò gbọdọ̀ wá sí ààfin láìmú ọkọ wá
Alhaja Lizzy Anjọnrin Lawal ti ọpọ maa n pe mi ibu owo Mama Florida, tun ti ja gudugbẹ ọrọ lulẹ lori irin ajo aye rẹ, ki o to ṣe igbeyawo.
Ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara, Lizzy ni ''gbogbo obinrin ni aṣẹwo, amọ, awọn ọkunrin ṣẹwo ju awọn obinrin lọ.''
Ṣugbọn Lizzy fikun ọrọ rẹ pe, awọn onitiata papa julọ awọn obinrin ninu wọn, lo ṣe ọmọluabi ju.
- Aláàfin fẹ́ gba bàálù kékeré bíi owó orí mi, ọkọ mi ń gbọn kiri - Lizzy Anjorin
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Ariwo ló ń mú owó wọlé fún mi, kò wù mí láti gbé ayé tó dákẹ́ rọ́rọ́ - Lizzy Anjorin
- Ọkọ mi kò fẹ́ràn oúnjẹ òyìnbó àfi ti ìbílẹ̀ - Lizzy Anjorin
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Ọkọ Lizzy Anjorin fí ẹ̀bùn ọkọ̀ N20m fi ta lọ́rẹ
- Lizzy Anjorin yòó ṣayẹyẹ ìkómọ ní ìlú mẹ́wàá ọ̀tọ̀tọ̀ l'Ámẹ́ríkà
Lizzy ṣalaye pe ''nigba naa lọun, Mr Lawal maa n fun mi lowo, o dẹ maa n dun mọ mi gan an.
Mr Lawal lo kọkọ gba ile fun mi niluu Eko nitori mi o nile nigba naa.
Nigba to to asiko fun mi lati yan, gomina ati ọba alaye wa lara awọn to kọ ẹnu ifẹ si mi, ṣugbọn kii ṣe Alaafin o.
Ẹ tiẹ gbọ na, ẹyin ti ẹ ni mo n fẹ Alaafin, bawo ni mo ti maa ‘handle’ baba?
Alaafin gan an lo sọ fun mi pe ti n ko ba ti mu ọkọ wa, n ko gbọdọ de aafin mọ.
Mo jẹ obinrin to jẹ pe awọn ọkunrin maa n nifẹ mi gan an.
Mo fẹ ra ''sperm'' lati bimọ nipa ilana ''surrogate'' tori ko si ohun to buru nibẹ.
Ṣugbọn ayẹwo fihan pe ọjọ igbeyawo mi gan an ni mo loyun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Goriola Hassan, má pe ara rẹ ní ọba Imobi-Ijebu mọ́, bí bẹ́ẹ̀kọ́... - Ilé aṣòfin Ogun
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Akintoye àti èèyàn 1m míì ń lọ àpéjọ UN lórí ìyapa Nàíjíríà
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Ọmọ ìyá méjì tó ń lọ ṣe ìdánwò NECO wà lára èèyàn márùn ún tí tírélà agbépo tẹ̀ pa n'Ibadan
Mi o kii n fẹ ki eeyan ṣe awọn nkan ti mi o le ṣe fun eeyan fun mi.
Bi a ti ni kọmiṣọnna, minisita atawọn ipo mii, ni emi naa ni ipo mi lawujọ ti ẹnikẹni ko mọ.
Iru awọn ọrẹ ti mo n ba a rin kii ṣe awọn ọrẹ ti ẹ le maa ri kaakiri.
Ti a ba ti ja tan, kiakia naa ni a maa ti ba ara wa ṣere pada, e wo ni ki a ku si idi ija?
Iwọ lẹnu ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fi ẹnu rẹ sọ nipa mi.
Ti temi ni pe ti ko ba ti si wahala nile mi atawọn ti a n jọ n gbe, ti arin emi ati Ọlọrun mi si dara, o ti tẹ mi lọrun.
Ninu ọrọ ọkọ rẹ, Alhaji Lateef Lawal Adegboyega sọ pe Lizzy ko ni aṣiri kankan niwaju oun.
O ni nigba ti oun pade Lizzy fun igba akọkọ, oun ko le kọ ẹnu si i tori oju n ti oun.
''Lẹyin ti a pade ara wa ti a si fi ara wa silẹ, mi o fẹ iyawo kankan titi di igba ti a fi pade ara wa.
Ṣugbọn mo ni awọn ti a jọ maa n gbe si ara wa lẹnu lasan an ni.
Igba ti a maa fi fẹ ara wa pada, ko si iyawo kankan lọdọ mi nigba naa.
Ọpọ lo n sọ pe iyawo mi ti fi ile ọmọ rẹ ṣe oogun owo ṣaaju igbeyawo wa.
Ọrẹ mi kan gan an beere lọwọ mi lọjọ keji igbeyawo wa pe se iyawo mi si le bimọ.
Iyawo mi lo jẹ, ko baa lowo ju Alakija lọ, ko tun ni ju mi lọ, o gbọdọ gbọ ọrọ si mi lẹnu.