Lizzy Anjorin: Kò sí òṣèré tíátà lóbìnrin tó ní dúkìá jù mí lọ

Ilumọọka osere tiata lobinrin, Lizzy Anjorin, ti kede faraye pe ọpọ eeyan ni ko mọ pe awọn ọkunrin kii fẹ nawo ọfẹ fun iru obinrin bii toun, to n sisẹ kara loju mejeeji

Lizzy Anjorin, lasiko to n takurọsọ pẹlu iwe iroyin adanilaraya kan salaye pe, oun ko setan lati gbara le ọkunrin kankan fun owo nina, idi si ree ti oun se n se laala lori okoowo katakara ti oun n se.

"Elo ni ọkunrin kan fẹ fun iru obinrin bi emi, ti yoo ka lẹnu? Owo osu ti mo n san fun awọn osisẹ mi gan losoosu lasan sun mọ miliọnu kan naira, elo wa ni ọkunrin kan fẹ fi fa mi loju mọra?"

Lizzy salaye siwaju si pe ọmọ sisẹ sisẹ ni oun, ti oun si maa n lọ soke okun lati lọ ra awọn asọ ati ẹsọ ara ti oun n ta ninu ile itaja oun to wa ni adugbo Ikọta nilu Eko.

"Tẹ ba ri awọn fidio ti mo n se lati polowo ọja mi, ẹ ri pe ojoojumọ ni mo maa n jo lati polowo awọn ọja naa. Ki n to lee ta asọ bubu kan soso, maa jo jo jo, ko si lee si akẹẹgbẹ mi kankan to lee sọ pe oun n sisẹ aje ju mi lọ."

Bakan naa ni Lizzy fẹ ki araye mọ pe oun si ni obinrin osere tiata to lowo julọ ni Naijiria nitori pe kii fi bo rara pe ko si akẹẹgbẹ oun kankan ti o ni dukia ti oun ni, tabi ti Ọba oke kẹ ju oun lọ.

"Iya mi lo sọ mi di eeyan ti mo da loni, oun si ni igi lẹẹyin ọgba fun ohun ti mo da loni, iya mi le pupọ, nitori emi nikan lo bi, o yẹ ko kẹ mi ra ni, amọ ko ri bẹẹ rara. Ti mo ba fẹ ohunkohun lati kekere, mo gbọdọ sisẹ fun ni, eleyi si lo ran mi lọwọ lati sisẹ kara fun owo."

Nigba ti wọn bi Lizzy leere nipa ohun to jẹ atọna fun, o dahun pe ipamọra ni ati oore ọfẹ Ọlọrun, pẹlu afikun pe eeyan gbọdọ le diẹ ko to lee se aseyọri okoowo nilẹ Naijiria nitori irora pọ ninu sise isẹ aje nilẹ yii.

"Mo nifẹ oge sise, mo si n sisẹ kara, Mo maa n ra awọn ọja asọ ati goolu to yatọ, ti ko si wọpọ. Idi ree ti awọn ọja ti mo n ta kii fi se iru wa, ogiri wa, wọn kii se gbarọ-gbudu. Ẹnikẹni to ba si ra ọja mi, to wọ ọ, yoo duro re nilẹ, ti yoo si dun wo."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni Lizzy fikun pe oun nifẹ goolu pupọ, ti oun si maa n de orilẹede meje lati wa goolu to yatọ, eyi to si dara ni oun maa n wa lọ lati ra.