Christmas: Ọlọ́pàá gbẹ́sẹ̀ lé yínyin ohun ìṣiré ọdún ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ẹnikẹni to ba yin ohun iṣire ọdun ti a mọ si banga nipinlẹ Ondo lasiko pọpọsinsin ọdun keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna yoo rugi oyin.

Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Adie Udie lo gbe ofin yii kalẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni ẹnikẹni to ba ta felefele to si tapa si aṣẹ yii yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.

Bakan naa lo ni gbogbo awọn to ba ṣowo ohun iṣire naa lasiko ọdun ti ọwọ ba tẹ ko ni ṣai jo lamba ofin.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ṣalaye pe agbepolaja nikan kọ lole, ẹni gba a silẹ gan an ole ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo wa fi kun un pe awọn ṣe tan lati pese abo to peye lasiko ọdun to wọle de naa.