Ife Chieftain: Ìlé ẹjọ́ rọ Obalufe ti Ile Ife lóyè

Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Ọṣun ti pa a laṣẹ fun Ọbalufẹ ti ilu Ile Ife, Oloye Idowu Adediwura lati shi'di kuro lori aga oye rẹ gẹgẹ bii Ọbalufẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ yii tun pa a laṣẹ fun Ọọni ti Ile Ifẹ, Ọba Adeyeye Ogunwusi lati tete di alafo ti iyọloye yii ṣi silẹ ni kiakia pẹlu ọmọ oye lati ile oye Aga laarin ọjọ mọkanlelogun.

Ẹni to kan lẹyin Ọọni ni Ọbalufẹ jẹ. Oun ni Olootu ijọba Ile Ifẹ.

Agbara ti Obalufẹ ko fi bẹẹ kere rẹpẹtẹ si ti Ọọni tori bi Ọọni ko ba si nile, oun lo laṣẹ koda bi Ọọni ba wa nile, oun lo n ṣakoso awọn oloye ọwọ ọtun nigba ti Ọọni gan n ṣamojuto apa keji.

Adajọ to da ẹjọ naa, Foluke Awolalu ati lorukọ ile oye Aga fi lelẹ pe ifinijoye Adediwura ko ba alakalẹ ofin ifinijoye mu.

Ṣaaju, ile ẹjọ ti wọgile iwe ti Adediwura fi ṣọwọ si wọn to n pe fun ki wọn fagile ẹjọ naa nitori awọn ẹjọ miiran wa nilẹ to so mọ ọ̀rọ̀ yii kan naa.

'Tori naa, ile ẹjọ sọ pe ni ilana akọsilẹ eto ifinijoye ni Ile Ife ti ọdun 1957, idile Aga lo kan lati fa Ọbalufẹ tuntun kalẹ kii ṣe idile Ajagbusiekun ti Adediwura ti wọn fi joye ti wa.

Lafikun, ile ẹjọ tun pa a laṣẹ pe Adediwura ko gbudọ gbe ara rẹ kiri bii Ọbalufẹ mọ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe agbẹjọro Adediwura, Babafemi Akande ṣapejuwe ẹjọ naa gẹgẹ bi eyi to tọ to si ye yekeyeke. O ni ifinijoye to ba ti wa ni akọsilẹ ti di ofin.

Ẹwẹ, "ko sẹni to kọja ofin ko si sẹni to kere fun ofin. Nitori naa adajọ ti da ẹjọ gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ", agbẹjọro Akande sọ bẹẹ.