Twitter ban in Naijiria: Ìjọba Nàìjíríà ṣàlàyé ibi tí ìjíròrò pẹ̀lú Twitter dé dúró àti ìgbà tó ṣeéṣe kí Twitter padà sẹ́nu iṣẹ́ ní Nàìjíríà

Minisita feto iroyin lorilẹede Naijiria, Lai Mohammed ti ṣalaye asiko to ṣeeṣe ki ijọba apapọ o gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de oju opo ikansiraẹni Twitter.

Bi ọrọ ti Minisita naa sọ lẹyin ipade igbimọ iṣejọba orilẹede Naijiria to waye nilu Abuja lọjọru ba ṣee tẹle, o ṣeeṣe ki ijọba gbẹsẹ kuro lori ofin naa laipẹ.

Ọgbẹni Lai Mohammed ṣalaye fun awọn akọroyin pe ijiroro pẹlu ileeṣẹ ikansiraẹni naa ti de ibi to lapẹrẹ, bẹẹni ojuutu si ọrọ naa ti n sun mọ etile.

Bakan naa lo tun tẹnumọ gbedeke ti ijsba Naijiria la kalẹ fun eegun Twitter lati tun lee ṣẹyọ ni Naijiria ninu eyi to ti mẹnuba pe ki ileeṣẹ Twitter fi orukọ silẹ gẹgẹ biileeṣẹ okoowoni Naijiria ki o si ni awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, ki o si maa san owo ori fun awọn alaṣẹ.

Amọṣa Ọgbẹni Mohammed ko ṣai tun sọ pe itẹsiwaju to loorin ti n waye laarin ijsba orilẹede Naijiria ati Twitter lọna ati yanju edeaiyede naa.

Ni ibẹrẹ oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ijọba orilẹede Naijiria fofin de Twitter ni Naijiria lẹyin ti ikanni ikansiraẹni naa yọ atẹjade kan ti aarẹ Buhari fi soju opo naa lori pe o tako ọkan lara awọn ilana rẹ.

Ninu atẹjade naa, Aarẹ Buhari ni awọn ajijagbara Biafra lẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria yoo ri ọwọ oun laipẹ pẹlu ede ti wọn yoo gbọ eleyi ti awọn kan tums si iwa ipa lati ọdọ aarẹ Naijiria naa.

Amọṣa o, ijsba Naijiria ti jade sita lati sọ pe igbesẹ awọn ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu yiyọ ti wọn yọ atẹjade aarẹ danu bikoṣe lati daabo bo alaafia orilẹede Naijiria.