Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rọ̀ bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf Ajikobi 1

Gbogbo ọ̀na ni Ọga mi Igboho ti fi sọ asọtẹlẹ iṣẹlẹ yii ṣaaju ko to ṣ\lẹ- Alhaji ajikobi 1

Okan lara awọn amugbalẹgbẹ Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ba BBC sọrọ lori ibi ti ija ominira Yoruba Nation yii de duro nile Igboho.

Alhaji Saheed Yusuf Ajikobi 1 ṣọ awọn ọrọ ti Sunday Igboho ba wọn sọ lori ominira Yoruba Nation lati tẹsiwaju laini fi ṣe ohunkohun n to ba ṣẹlẹ.

Alhaji Saheed ni Sunday Igboho jẹ oloju aanu ti ko si ẹni to sunkun de ile rẹ ti ko ba ẹrin jade.

O sọ bi Igboho se n saanu awọn eeyan lorisirisi ti Igboho ko fẹ ki iya jẹ ẹnikẹni ni sakani rẹ.

Ajikobi 1 tun sọ pe ija ominira Yoruba Nation n tẹsiwaju lai naani gbogbo idojuko ti wọn n ri bayii nile Igboho ati kaakiri.

Sunday Igboho ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fún àwa mẹ́rin nínú amúgbálẹ́gbẹ̀ rẹ̀- Alhaji Yusuf

Bakan naa lo gba pe ija ominira Yoruba Nation jẹ ajọja fun ọpọ eeyan ti ko bẹru nkan ti yoo ṣẹlẹ.

O ni igbesẹ gbogbo awọn to wa nile Igboho lasiko yii ni lati bọwọ fun ofin pẹlu idupẹ lori idajọ Adajọ to waye lọsẹ yii lori ọrọ Oloye Igboho.