LAgos Snack For Thought: UNICEF ní akẹ́kọ̀ọ́ 229,264 ló kúrò níléẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, UNICEF
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé òun yóò ṣe àfilọ́lẹ̀ ètò ìsúná òní bílíọ̀nù mọ́kànlá náírà láti máa fún àwọn ọmọ ilé ìwé ni ipanu lasiko ikẹkọọ.
Olùbádámọ̀ràn pàtàkì lórí ìfikùlukù pẹ̀lú ará ìlú nipinlẹ Eko, ọmọọbabirin Aderemi Adebowale lo sọ èyí di mimọ, lásìkò tó ń já bọ̀ àṣeyọrí ọdún méjì ìṣejọba gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwoolu ni Alausa Ikeja.
Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, ètò ìpèsè ipanu fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n pe àkọlé rè ni "Snacks for Thought" yóò seranwọ fún eto oúnjẹ iléèwé tí ìjọba àpapọ̀ gùnlé tẹ́lẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo àwọ́n lọ́balọ́ba tó ti ṣàtìlẹ́yìn jíjá fún Oduduwa Nation ní ilẹ̀ Yorùbá
- Ìròyìn àyọ̀! Wọ́n tí tú akẹ́kọ̀ọ́ FUNAAB tí wọ́n jígbé sílẹ̀, bí orí ṣe kó o yọ rèé
- 'Ìyà ń jẹ́ wá o! Owó osù mẹ́jọ́ há sọ́wọ́ Akeredolu, ẹ́ bá wa wá bẹ̀ ẹ́'
- Ọdún 32 ni mo fi ṣiṣẹ́ oko mọ́ ìṣẹ́ tíṣà kí àwọn ọmọ mi le jẹ́ èèyàn, àmọ́ ikú mú Taiwo lọ - Baba Taiwo Asaniyi
- Njẹ́ o mọ̀ pé iléèṣẹ́ kan ní UK ti ra orúkọ́ ẹ̀yà Yorùbá tí ẹlòmìí kó fi ní le lò ó?
Adebowale fikun pe eto ipese ipanu naa lo wá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ipele ikini sì ìkẹta nìkan.
Ó tún ṣàlàyé pé eto yìí yóò na ìjọba ní bílíọ̀nù mọ́kànlá náírà "A ni ifọwọ́sọwọ́pọ̀ pelu ilé iṣẹ́ lórí eyi, a sì ti ní ènìyàn irínwó tó ti ṣetán láti ṣe iṣẹ́ fún wa lofẹ̀ẹ́"
Adebowale fi kún pé, ó se pàtàkì láti ṣe èyí kì àwọn lè mú adinku bá bí àwọn ọmọ ṣe ń kúrò ní ilé ìwé ni ìpínlẹ̀ Eko.
O ni èyí ló jẹyọ nínú àbájáde ìwádìí ajọ UNICEF pé awọn akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun Okoolerugba o le mẹsan, (229,264) lọ kúrò ní ilé ìwé nipinlẹ Eko lọ́dún 2018.
"Lójúna àti mú adinku bàa iye àwọn akẹkọọ ti yoo duro kawe, a nílò jú owó isuna lásán lọ, àwọn ìrànwọ́ ijoba bí èyí yóò mú ìyàtọ̀ wá nípa fífi ọmọ sì ilé ìwé.
Bákan náà lo ni igbesẹ naa yóò mú adinku bá ìwà ọ̀daràn láwùjọ."














