You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kaduna killings: Gómìnà El-Rufai kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí àwọn tó kú
Awọn janduku agbebọn tun ti ṣekupa eeyan mẹtala ninu ikọlu mii to waye ni ijọba ibilẹ Zangon Kataf, Kauru ati Chikun nipinlẹ Kaduna.
Kọmiṣọna fun ọrọ abẹle ati ọrọ aabo nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ṣalaye pe, ileeṣẹ ologun ti fidi ọrọ naa mulẹ.
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, awọn janduku naa kọlu Irmiya Godwin ati aburo rẹ, lẹyin ti wọn de lati oko wọn to wa ni ijọba ibilẹ Zango Kataf.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọwọ́ Sunday Igboho tẹ ‘Sọ́jà’ àti aráàlú mẹ́rin tó ní wọn ń dọdẹ òun
- Gani Adams àti Seyi Makinde ṣèpàdé, àbọ̀ wọn rèé
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Sunday Igboho ṣẹ̀ sí òfin ète ìdìtẹ̀ gbàjọba, ó sì le fojú winá òfin - Amofin
- Bí ọlọ́pàá bá tó bẹ́ẹ̀, kó dá wa lọ́nà, Yoruba kìí ṣe ara Naijiria mọ́ - Sunday Igboho
- Ẹ gbọ́ ná, kí ló lè mú kí àfín 114 di àwátì?
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Akẹ́kọ̀ọ́ kò yọjú sílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn tí àwọn olùkọ́ padà sẹnu iṣẹ́ nílèèwẹ tí rògbòdìyàn Hijab ti wáyé n'Ilorin
Wọn ṣekupa Godwin, amọ aburo rẹ mori bọ, o si sa asala fun ẹmi rẹ.
Bakan naa lawọn janduku ọhun tun kọlu abule Kizachi ni ijọba ibilẹ Kauru nibi ti wọn ti pa eeyan mẹwaa, ti eeyan mẹrin si farapa.
Ile mẹrindinlọgọta ati alupupu mẹrindinlogun ni wọn dana sun, koda wọn tun sọ ina si aba ti awọn eeyan abule naa ko ere oko si.
Orukọ awọn tawọn janduku ọhun pa gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ ni Esther Bulus ati ọmọ rẹ ti ko ju ọdun kan lọ, Maria Bulus, Lami Bulus, Aliyu Bulus.
Awọn yoku ni Monday Joseph, Geje Abuba, Wakili Filibus, Yakubu Ali, Dije Waziri ati Joseph Ibrahim.
Cecilia Aku, Yakubu Idi, Godiya Saleh, Moses Adamu ni awọn eeyan to ṣeeṣe ninu ikọlu naa, wọn n gba itọju lọwọ nile iwosan bayii.
Bakan naa, awọn agbebọn ṣekupa Duza Bamaiyi ni abule Masaka ni ijọba ibilẹ Chikun, nibi ti eeyan meji ti farapa.
Wọn tun pa Zakka Pada ni abule Kurmin ni ijọba ibilẹ Chikun kan naa.
Ẹwẹ, gomina Nasir El-Rufai ti kẹdun pẹlu awọn ẹbi oloogbe, o si gbadura pe ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.