You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Àsìkò ti tó, ẹ̀yin ọmọ Yoruba tó ń bẹ lókè ọya, ẹ máa padà bọ̀ nílé
Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti ke si gbogbo ọmọ Yoruba to wa loke ọya lati pada wale nitori ile ti to lọ, ati pe asiko ti to lati da orilẹ-ede to jẹ ti ọmọ Yoruba silẹ.
Igboho lo sọ ọrọ naa nibi ipade kan ti Ọjọgbọn Banji Akintoye, to jẹ aṣiwaju nilẹ Yoruba naa wa.
O ṣalaye pe ko si nnkankan to n jẹ iṣọkan Naijiria mọ lẹyin ti eto abo ilẹ Yoruba mẹhẹ, ti ijọba apapọ ko si ri ohun kankan ṣe nipa rẹ.
Bakan naa lo tun ṣalaye pe oun atawọn ikọ oun ti ṣetan lati koju awọn ọdaran Fulani lọna ati le wọn kuro ni gbogbo ilẹ Yoruba patapa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "a o lọ ṣi awọn ẹnu ibode wa ti ijọba apapọ ti pa, a o si ṣigbogbo rẹ ki ounjẹ le maa wọle."
"A kii ṣe ara Naijiria mọ, ọlọpaa ti wọn ba bi daa, ko da wa lọna tabi ko gbiyanju lati mu ẹnikẹni ninu wa, igba yẹn ni wọn yoo mọ pe ẹnu Yoruba ko."
Igboho sọ pe ko si anfani kankan ti ẹya Yoruba n ri ninu Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede nitori gbogbo ipo to ṣe pataki ninu ijọba to wa lode yii ni Hausa n ṣakoso.
O pari ọrọ rẹ pe digbi ni oun wa lẹyin awọn agbagba Yoruba lori igbesẹ wọn lati gba ominira kuro ni Naijiria.
A ń lọ ṣí ẹnu bodè Yorùbá tíjọba tìpa sílẹ̀, kí oúnjẹ wọlé nírọ̀rùn - Sunday Igboho
"A ko fẹ Fulani mọ nilẹ Yoruba, a fẹ́ maa se akoso ara wa funra wa ni."
Igbe ti ajijagbara ọmọ Yoruba, Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho fi bọ ẹnu niyii, nibi ipade apapọ ọmọ Yoruba.
Igboho, ẹni to gbarata lori eto aabo to mẹhẹ nilẹ Yoruba ati bi awọn ọdaran darandaran kan se n pa ọmọ Yoruba tun ni ''ogun ka maa le su, ka maa le tọ nitori aibalẹ ọkan nilẹ Yoruba ti to gẹ.''
- Ọ̀daràn Fulani pa ọmọ mí, jó ile, ọ̀kọ́, tí ìlú wa sì di ahoro - Ará Yewa l‘Ogun figbe ta
- Ẹ múra mi sílẹ̀ ẹ̀yin apààyàn Fulani ní Ogun, mò ń bọ̀ kánkán - Sunday Igboho
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- 'Ọkọ̀ ńlá méjì ló kó àwọn Fulani wọ Ajowa Akoko ní Ondo, àmọ́ a ti jọ ń sọ̀rọ̀ pé ...'
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
''Kilode gan an? A n rin, ọkan wa ko balẹ, ka ma le sun, ka ma le tọ, a n gbe inu ile wa, ọkan wa ko balẹ, Ki lo de? ṣe ẹru ni wa ni?
Gbogbo awọn to di ipo olori mu ni ibudokọ ọkọ oju-omi Tincan Island ati ibudokọ ọkọ oju-omi yoku to wa niluu Eko, Fulani ni wọn, a ko fẹ wọn mọ.''
A n lọ si awọn ẹnu ibode Yoruba silẹ ki ounjẹ le wọle ni irọrun
Igboho ni bakan naa lọmọ ṣori lawọn ibode Naijiria to wa nilẹ Yoruba, o fi ibode Idi Iroko ṣe apẹẹrẹ nibi ti Fulani ti jẹ ọga agba ileeṣẹ aṣọbode.
''Awa ọmọ Yoruba ni lati ṣe ipade bi awọn ibode wa yoo ṣe di ṣiṣi, ki irẹsi atawọn nkan mii le maa wọle ni irọrun,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
Ajijagbara ọmọ Yoruba ni ''o ti to gẹ, gbogbo ibode wa ni ijọba apapọ ti gbe tipa, a si n fi asiko yii sọ fun wọn pe a ko si labẹ wọn mọ.''
Igboho ni ''awa gan an ti ṣetan fun gbogbo ohun ti ijọba ba fẹ ṣe fun wa, mo n gba ẹnu gbogbo ọmọ Yoruba ni o."
Ẹnu Yoruba ko, irọ ni pe ẹnu wa ko ko
Ajijagbara naa wa fi ọwọ gbaya pe isọkan ati irẹpọ wa laarin awọn ọmọ Yoruba, ko si si iyapa mọ laarin wọn.
Igboho ni "awọn eeyan kan le maa sọ pe ẹnu Yoruba ko ko, ẹ maa fọkan si rara, ti ẹ ba fẹ mọ boya ẹnu wa ko tabi ko ko, ẹ fi ọwọ kan ẹnikẹni ninu wa.''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- A kọ òrìṣà babańlá wa sílẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀daràn darandaran máa pa wá bí ẹ̀fọn - Àwọn Oníṣẹ̀ṣe
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Ààrẹ Tanzania, John Magufuli tó jáde láyé
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
- Krìsìtẹ́nì àti Mùṣùlùmí ń sọ òkò lura wọn ní Ilorin torí aáwọ̀ lílo Hijab
- Wo ibùdó tó sún mọ́ ọ láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 l'Eko
- El Rufai àtàwọn gómìnà míì ló n tako sísan owó oṣù tó kéré jùlọ - NLC
- Ilé ẹ̀kọ́ 10 tíjọba Kwara tìpa di ṣíṣí padà, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin le lo Hijab níbẹ̀
- Boko Haram gboró, ó dáná ṣun ìbùdó ológun, iléẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn
Ọba alaye nilẹ Yoruba to ba ni oun ko se tiwa ko ni pẹ
Bakan naa ni Sunday Igboho fi da gbogbo ọmọ Yoruba loju pe gba gba gba lawọn ọba alaye nilẹ Yoruba n bẹ lẹyin oun fun iwa ijijagbara ti oun n se.
Igboho sọ pe ''gbogbo ọba alaye ilẹ Yoruba lo wa lẹyin wa, ọba to ba wa ni oun ko si lẹyin wa, ki o lọ ṣe fidio lori ayelujara ki a ri, ko ni di ọjọ keji.''
Ọmọ Yoruba to wa nilẹ Hausa, ẹ maa bọ nile
Ajijagbara ilẹ Yoruba naa wa ke pe awọn ọmọ Yoruba to wa lapa oke ọya Naijiria pe ki wọn maa bọ wale.
Igboho ni imọran ti oun ni, ni oun n gba awọn ọmọ Yoruba to wa loke ọya naa pe ile to lọ.
"Ẹ maa bọ nile o, iya to n jẹ wa ti to gẹ, asiko ti to, ile ti ya, ẹ jẹ ka se ara wa ni ọkan soso.
''Asiko ti to, ile ti ya, ẹ jẹ ki a ṣe ara wa ni ọkan,'' Igboho lo sọ bẹẹ.