You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osugbo: Elebuibon ní awo ni yóò ṣìnkú ọba tó ṣètùtù kó tó dépò, kìí ṣe Alfa tàbí Pásítọ̀
Araba Awo tilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti salaye fun BBC Yoruba nipa ohun to rọ mọ ọba jijẹ, ẹsin to n se ati ilana sinsin oku rẹ.
Elebuibon salaye awọn ọrọ yii lasiko to n ba BBC sọrọ nipa bi awọn ẹgbẹ awo Osugbo se lọ fi tipa gbe oku ọba to waja.
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin nipa bi ẹgbẹ awo Osugbo se fi tipa gbe oku ọba kan pamọ nilẹ Ijebu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- O kéré sí Number! 'Àwa ológún ò fi ara wa wọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti máa ṣe alamí lórí irú ẹ Sunday Igboho'
- 'Èmi Alake yóò bi àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ àtàwọn Ogboni ná bí mo bá tilẹ̀ máa tako Sunday Igboho ámbọ̀sìbọ́sí...'
- Wo ibùdó tó sún mọ́ ọ láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 l'Eko
- El Rufai àtàwọn gómìnà míì ló n tako sísan owó oṣù tó kéré jùlọ - NLC
- Ilé ẹ̀kọ́ 10 tíjọba Kwara tìpa di ṣíṣí padà, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin le lo Hijab níbẹ̀
- Boko Haram gboró, ó dáná ṣun ìbùdó ológun, iléẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn
- Ajínigbé jí Oba Imope gbé ní Ogun, wọ́n pa olódẹ tó fẹ dóòlà Kábíyèsí, N200M ni wọ́n ń béèrè
Iroyin naa ni awọn mọlẹbi ọba naa ni ko fẹ ki wọn sin baba wọn nilana ẹsin ibilẹ eyi to mu ki wọn gba ile ẹjọ lọ.
Ta lo lẹtọ lati sin oku ọba, mọlẹbi ni tabi awọn awo?
Nigba to n dahun ibeere lori ẹni to lẹtọ lati sin oku ọba to ba waja, Elebuibon ni kii se mọlẹbi lo lẹtọ lati sin oku ọba rara.
O ni niwọn igba ti ọba kan ba ti gori itẹ, o ti di ti gbogbo aye, oku rẹ si ti di ti araalu ati gbogbo eeyan.
"Oku ọba to ba waja kii se ti mọlẹbi mọ, awọn to lẹtọ lati sin oku rẹ naa lo lọ gbe oku naa pamọ.
Boya ọba ko wa sọ fawọn mọlẹbi rẹ tẹlẹ ni pe oun ti se oro, lo mu ki wọn pe awọn Osugbo lẹjọ."
Araba Awo ilu Osogbo fikun pe ọba kọba to ba jẹ kii se ti mọlẹbi rẹ mọ, wọn ko si lẹtọ mọ lati pasẹ lori isinku rẹ.
Se ọba ni anfaani lati sọ asọtẹlẹ pe ki wọn sin oun nilana ẹsin Islam tabi ti Kritiẹni?
Ọpọ igba ni isẹlẹ ti waye saaju nipa awuyewuye to maa n waye nidi ilana sinsin oku ọba to ba waja.
Bakan naa nirufẹ isẹlẹ yii waye saaju nilu Abeokuta nigba ti mọlẹbi Alake tilẹ Ẹgba tẹlẹ, ọba Lipede waja faake kọri fawọn ọmọ ẹgbẹ Ogboni.
Wọn ni Kabiyesi naa ti sọ asọtẹlẹ saaju pe ilana Kristiẹni ni ki wọn fi sin oun, nitori oun ti di ọmọlẹyin Kristi tootọ, ki oun to tẹri gbasọ.
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí márùn ún míràn lórí ikú ọmọ Fasoranti
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
- El Rufai àtàwọn gómìnà míì ló n tako sísan owó oṣù tó kéré jùlọ - NLC
- CCTV yọ Barry Jhay lórí ikú Kashy, òtítọ̀ ọ̀rọ̀ fojú hàn nígbẹ̀yìn
Nigba to n sọrọ lori asa ki awọn ọba kan maa sọ asọtẹlẹ fawọn mọlẹbi wọn lori ọna ti wọn fẹ ki wọn gba sin wọn, Elebuibon ni eyi ko tọna.
"Yoo dara ki ẹni to ba fẹ ki wọn sin oun nilana ẹsin igbalode Kristiẹni abi Musulumi ma kuku wulẹ jọba rara.
Ki wọn to fi ọba jẹ, o ni oro ti wọn yoo se, ti ọba ba si tun ku, o ni oro ti wọn yoo se pẹlu. Ẹni to ba wa jẹ Kristiẹni abi Musulumi, ẹ ma wulẹ jọba.
Ẹ fun ẹni to setan lati se isẹse laaye lati jọba, ka le yago fun awuyewuye ti ko tọna."
Ewu wo lo wa ninu ka sin ọba to se oro nilana ẹsin Igbalode?
Araba Awo, lasiko to n salaye awọn ewu to rọ mọ ilana sinsin ọba ni ilana ẹsin igbalode salaye pe ewu n bẹ loko longẹ fun oku ọba to ba waja naa.
"Oku ọba ti wọn ko ba fi etutu tabi isẹse sin yoo ni idiwọ nla lẹnu irinajo rẹ. Awọn ara ilẹ to yẹ ko ba pade ni yoo nira fun lati ri, eyi to lewu pupọ.
Bakan naa, iru ọba to waja yii ko pese ọna to tọ silẹ fun ẹlomiran to fẹ jẹ ọba lẹyin rẹ, eyi naa si lee mu idiwọ nla lọwọ.
O yẹ ki wọn se bi wọn se n se lati igba iwasẹ, ko le ri bo se yẹ ko ri, bi bẹẹ kọ, o lewu."
Jerusalem tabi Arab kọ ni wọn ti bi wa, alawọ dudu ni wa
Oloye Ifayemi Elebuibon wa rọ ile ẹjọ lati bọwọ fun asa ati isẹse agbegbe kọọkan nilẹ Airika ati ba se n gbe igbe aye wa.
"Ilẹ alawọ dudu Afirika la wa, adajọ gbọdọ bojuwo eyi. Bi eeyan kan ba ni oun n se Musulumi, kii sa se ilẹ Arab ni wọn ti bi.
Bakan naa, ẹni to ba ni oun n se Kristiẹni, kii se ilẹ Jerusalem ni wọn ti bi, bi wọn ti n se ni ilẹ Jerusalem ati Arab yatọ si tilẹ Afirika."
Ẹgbẹ́ Òṣùgbó fi tipá gbé òkú Ọba ní Ijebu, mọ̀lẹ́bí fárígá
Ta lo ni ẹtọ lati sin oku ọba alaye to ba waja, ẹgbẹ awo to n dari ilu lo gbọdọ sin ọba ni ilana ibilẹ ni abi mọlẹbi ọba?
Bakan naa, ilana isinku wo lo yẹ ki wọn fi sin oku ọba, se ilana ẹsin ti ọba ba n sin ni abi ilana isẹse to gba jọba ninu ilu?
Ohun aburu wo lo le sẹlẹ ti wọn ko ba sin ọba nilana ẹsin ibilẹ, ti wọn si sin nilana ẹsin Kristiẹni abi ti Musulumi?
Awọn ibeere yii ati ọpọ miran lo n tawọ tasẹ ninu awọn ọmọ Yoruba to gbọ nipa isẹlẹ kan to waye nilu Aba Ayepe.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Trust ti jabọ rẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ awo Osugbo lo fi tipa gbe oku Alaye-Aba tilu Aba Ayepe kuro nibi ti awọn mọlẹbi tọju oku ọba naa pamọ si.
Ọjọ Kejilelogunosu Kinni ọdun 2021 ni Ọba Rauf Adebayo Raji-Suleimon, Alaye-Aba tilu Aba Ayepe, dara pọ mọ awọn baba nla rẹ, tawọn mọlẹbi rẹ ko si fẹ sin nilana ẹsin ibilẹ.
Ọna lati daaabo bo isẹse lo mu kawọn ọmọ ẹgbẹ awo Osugbo ya wọ ibi ti oku naa wa, ti wsn si lọ gbe pamọ nilana ẹsin ibilẹ, eyi to bi awọn mọlẹbi ori ade to di oloogbe naa ninu.
Ki lo ṣẹlẹ nigba ti ẹgbẹ awo Osugbo fi tipa gbe oku ọba?
Ọrọ di isu ata yanan-yanan, tawọn mọlẹbi ọba si wọ ẹgbẹ Osugbo lọ sile ẹjọ pe wọn tako ẹtọ tawọn ni lati fun baba awọn ni ẹyẹ ikẹyin nilana ẹsin Musulumi.
- Àwọn agbébọn jí èèyàn méjì gbé ní ibùdó tí wọ́n tí ń fọ́ òkúta ní Ibadan
- Agbẹnusọ Sunday Igboho ná N2.5m bíí owó oúnjẹ́ lásán, gbas gbos bẹ̀rẹ̀
- "Torí ₦20, ọlọ́pàá yìnbọn fún mi lọ́rùn, n kò sì le b'óbìnrin lòpọ̀ mọ́ tàbí bímọ''
- Bí Buhari kò bá ṣọ́ra, àwọn ọba alayé ni yóò ṣaájú ìjìjàgbara fún Yorùbá - Sunday Igboho
- Èèyàn mẹ̀rin kú, 189 wà nílé ìwòsàn torí ayédèrú ohun mímu tí wọn mu
Awọn mọlẹbi ọba naa ni Mususlumi ododo ni ọba naa ko to waja, o si yẹ ki wọn sin ori ade naa nilana ẹsin Islam ni.
Ẹjọ naa si lo pe awọn eeyan mẹẹdogun wa sile ẹjọ lati jẹjọ, awọn si lo jẹ ọmọ ẹgbẹ awo Osugbo nilẹ Ijebu nigbati igbimọ afọbajẹ tilẹ Ijebu lapapọ jẹ Olujẹjọ kẹrindinlogun.
Mọlẹbi ọba naa wa n beere miliọnu lọna aadọta naira gẹgẹ bii owo gba ma binu fun bi ẹgbẹ awo Osugbo se tẹ ẹtọ wọn mọlẹ ati ti ọba to waja pẹlu.
Awọn ọmọ ẹgbẹ awo Osugbo wọ asọ iṣẹṣe lọ sile ẹjọ
Amọ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ Osugbo ọhun n yọju sile ẹjọ to n gbọ ẹjọ naa nilu Abeokuta lati wa jẹjọ, se ni awọn ẹgbẹ awo naa wọnu gbọngan ile ẹjọ pẹlu asọ awo.
Bakan naa ni wọn n kọ orin isẹse to jọ mọ ẹgbẹ awo wọn, eyi ti wọn fi n tako ẹjọ naa ti idile ọba to waja pe wọn.
Adajọ ti wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Kẹrindinlsgbọn osu Kẹrin ọdun 2021.