You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fatai Aborode: Bàbá olóògbé ní kò sí ẹni tí kò le bẹ Fulani lọ́wẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ibi
Alhaji Lasisi Folorunso Aborode, to jẹ baba Ọmọwe Fatai Aborode, tun ti ṣalaye siwaju sii lori iku to pa Ọmọwe Fatai Aborode.
Ọmọwe Fatai Aborode lawọn janduku agbebọn kan ṣekupa niluu Igangan lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo.
Baba Aborode, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe eekan ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lagbegbe Ibarapa, Alagba Olawuwo tawọn ọlọpaa fẹsun kan pe o lọwọ ninu iku ọmọ oun, lo maa n tako ọmọ oun tẹlẹ lagbo oṣelu lati ọjọ pipẹ.
- Yorùbá kò fún Sunday Igboho láṣẹ láti dá orílẹ̀èdè Oodua sílẹ̀ - Yemi Farounbi
- Bí ọlọ́pàá bá tó bẹ́ẹ̀, kó dá wa lọ́nà, Yoruba kìí ṣe ara Naijiria mọ́ - Sunday Igboho
- Ọ̀daràn Fulani pa ọmọ mí, jó ile, ọ̀kọ́, tí ìlú wa sì di ahoro - Ará Yewa l‘Ogun figbe ta
- Ẹ múra mi sílẹ̀ ẹ̀yin apààyàn Fulani ní Ogun, mò ń bọ̀ kánkán - Sunday Igboho
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- 'Ọkọ̀ ńlá méjì ló kó àwọn Fulani wọ Ajowa Akoko ní Ondo, àmọ́ a ti jọ ń sọ̀rọ̀ pé ...'
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
Lori ahesọ ọrọ kan to n ja rain pe awọn afurasi Fulani darandran lo ṣeku pa Ọmọwe Aborode, baba oloogbe ni ko si ẹni ti ko le bẹ awọn Fulani niṣẹ, lati ṣeeyan nibi.
''Olawuwo tako Ọmọwe Aborode nigba ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, asiko naa ni wọn fi Aborode jẹ oye alakoso ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ibarapa.
Olawuwo sọ pe Aborode kere, ẹni to lo ọdun mẹẹdogun niluu Oyinbo ko too gba oye Ọmọwe, o ni ko le ṣiṣẹ yẹn.
Ṣugbọn ẹgbẹ PDP ni Ọmọwe Aborode koju osunwọn fun ipo ti wọn fun un, ati igba naa ni wọn ti gbogun ti i."
Alhaji Aborode ni idi ree ti Aborode ṣe fi PDP silẹ nigba naa niyẹn, amọ ọrẹ rẹ kan, Remi Oseni lo bẹ ẹ pe ko pada sinu ẹgbẹ naa.
Alhaji Aborode tun sọ pe akọwe fun ọmọ oun naa tun gbabọde fun un lori ọrọ iku rẹ.
Ọ́lọ́pàá gbé èèkàn PDP l'Oyo lọ ileẹjọ́ lórí ikú Fatai Aborode
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ ti tẹ eekan ọmọ ẹgbẹ oselu PDP kan lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo lori iku Fatai Aborode.
Oluwarẹ ni alagba Olawuwo, tii se gbajumọ oloselu kan nilu Igangan.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lowurọ ọjọ Ẹti, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sisọ loju rẹ pe, wọn ti gbe alagba Olawuwo lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o lọwọ ninu iku agbẹ ati oloselu naa lagbegbe Ibarapa.
Fadeyi ni lọwọlọwọ bayii, wọn ti fi eekan ọmọ ẹgbẹ oselu PDP naa sahamọ ninu ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi pari lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan-an.
"Wọn ti fi to mi leti pe awọn ẹsun kan wa ti wọn fi kan alagba Olawuwo nipa iku oloogbe naa, a si ti gbe lọ sile ẹjọ, amọ adajọ ti ni ka fi pamọ sinu ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi pari."
Iroyin kan ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP ti n lọ ki alagba Olawuwo naa ni ileesẹ ọlọpaa to n dena iwa ijinigbe to wa ni Dugbe, nilu Ibadan.
Bẹẹ ba gbagbe, Ọmọwe Fatai Aborode jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu PDP nilu Igangan lagbegbe Ibarapa, to si tun jẹ agbẹ alada nla to ni ọpọ eeka oko to fi gbin eso kasu.
Ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanla osu Kejila ọdun 2020 ni awọn agbebọn kan da Aborode to tilu eebo wa dale isẹ silẹ, lọna ni aago marun irọlẹ lasiko to n pada lọ sile latinu oko rẹ.
Ahesọ ọrọ kan lo ti n ja rain nilẹ pe awọn afurasi ọdaran Fulani kan lo sekupa ọmọwe naa.
Iku Ọmọwe yi si lo bi ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ninu, to fi lọ fun Seriki Fulani nilu Igangan ni gbedeke ọjọ meje lati ko aasa rẹ kuro nilu naa.
Isẹlẹ yii si lo n fa awuyewuye lọwọ, ti ko tii tan nilẹ.
A o ranti pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde gan kede nigba kan pe wọn ti fi to oun leti pe iku Fatai Aborode ni ohun se pẹlu ọrọ oselu.