You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigerian Labour Congress: Ewú ńbẹ! tí ìjọba ìpínlẹ̀ bá sàkóso gbèndéke owó oṣù òṣìṣẹ́,wọ́n ò ní san N30,000, N10,000 ní wọ́n má á san
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria ti ni awọn yoo bẹrẹ ifẹhọnu tako igbese awọn asofin lati gbe aṣẹ gbedeke owo oṣu oṣiṣẹ kuro ni ọdọ ijọpa apapọ lọ si abẹ aṣẹ ipinlẹ.
Eyi ko ṣẹyin abadofin ti ile aṣofin n da aba lati gbe aṣẹ kuro ni abẹ ijọba apapọ lọ si abẹ aṣẹ ijọba ipinlẹ wọn, ti wọn n pe ni ''Exclusive List to Concurrent List''.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Ayuba Wabba ni iwa ijẹkujẹ awọn oloṣelu lo mu ki wọn fẹ fi iya jẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria.
- Ẹni tó tẹ̀é mi lọ sílé ẹjọ́ ti ayé ń pariwo kìí ṣe Aláfọ̀ṣẹ rárá bíkòṣe...- Sowore
- Chimamanda Adichie pàdánù bàbá, ìyá láàrín ọdún kan, kíló ṣẹlẹ̀?
- Àwọn ajínigbé fìyà jẹ́ wa lọ́nà igbó tí wọ́n kó wa lọ- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GSS Zamfara
- Isiaka Jimoh EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isiaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isiaka
Wabba ni awọn ijọba ipinlẹ yoo san owo perete fun awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn ba gba wọn laaye lati ma a san owo oṣu oṣiṣẹ.
''Abẹ ofin agbaye ni o wa wi pe ijọba apapọ ni yoo ma a ṣeto gbendeke owo osu awọn oṣiṣẹ kii ṣe ijọba ipinlẹ''
'Wabba ni: 'Nitori naa, a ko ni gba ki awọn aṣofin rẹ wa jẹ nitori iwa ijẹkujẹ ati ifiyajẹ ara ilu ti wọn ma n ṣe''
''Labẹ ofin Naijiria, owo kan naa ni awọn oloṣelu ti wọn n yan si ipọ n gba lai wo ọrọ ajẹ tabi awọn alakalẹ miran''
Ni afikun, adari ajọ naa ni: ''Kilode to wa jẹ ọrọ awọn oṣiṣẹ to yẹ ko pọn dandan fun wọn ni wọn yoo wa ma a dinku''
''Nitori ti a ba fi awọn ipinlẹ silẹ ki wọn ma a pa aṣẹ lori gbendeke owo osu oṣiṣẹ, awọn miran ko ni san 30,000 naira gẹgẹ bi gbendeke, 10,000 naira ni wọn yoo maa san.''
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
- Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lé e jáde
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Covid 19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria
- Ẹ kó àwọn ọkọ̀ yín tó ti dẹnukọlẹ̀ kúrò lójú popo tàbí kí a gbẹ́sẹ̀lé wọn- FRSC sí àwọn awakọ̀
- Ohun tó yẹ kí ó mọ̀ nípa oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ ìbàdí rè é
Wabba ni: ''Nitori naa ni a gbọdọ tako abadofin naa nitori ipinya ni wọn fẹ mu ba awọn oṣiṣẹ, bi awọn oṣelu ṣe n pin awọn eniyan nipa ẹsin ati ẹya ni Naijiria''
Bakan naa ni Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Ayuba fikun wi pe ni Ọjọọru, ọṣẹ to n bọ ni awọn yoo bẹrẹ ifẹhọnuhan kaakiri awọn ipinlẹ ni orilẹ-ede Naijiria ni awọn ile aṣofin kaakiri Niajiria ati ile Asofin ni ilu Abuja.
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
- Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà
- Ọlọrun má jẹ́ kí a jẹ́ gbèsè lókù báyìí tí a kò kó ọjá lọ sílẹ̀ Yorùbá mọ́- Hausa Oníṣòwò
- Ẹni tó tẹ̀é mi lọ sílé ẹjọ́ ti ayé ń pariwo kìí ṣe Aláfọ̀ṣẹ rárá bíkòṣe...- Sowore
- Chimamanda Adichie pàdánù bàbá, ìyá láàrín ọdún kan, kíló ṣẹlẹ̀?