You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wakili Arrest: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC tó mú Wakili sílẹ̀
Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta ti ileeṣẹ ọlọpaa ti mọle lori ẹsun wi pe wọn mu Wakili ti gba itusilẹ kuro ni agọ ọlọpaa lẹyin ti wọn gba oniduro wọn.Wọn kuro ni atimọlẹ ọlọpaa to n bẹ ni Iyaganku nilu Ibadan ni nnkan bi i aago mẹfa irọlẹ ku ogun iṣẹju l'ọjọ Iṣẹgun.
Itusilẹ naa ko se lẹyin igbesẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ati Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams.
- Kí ló gbé Barry Jhay ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde Barrister dé gbaga ọlọ́pàá?
- Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams
- Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje
- Nkán ìbànújẹ ni bí ọlọ́pàá ṣé ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC mọ́lé nítorí Wakili- Adari OPC
- Áwa Hausa tá a wà l'Ogbomoṣọ ti di Yorùbá- Oba Haruna Sabo Ogbomoso
- Ọ̀rọ̀ aàbò ní Nàìjíríà ti di kí olórí dorí ẹ mú- Femi Falana
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
Adari OPC nipinlẹ Ọyọ, Arakunrin Rotimi Oguntunde ti gbogbo eeyan mọ si "Olumọ", alamọran pataki si gomina ipinlẹ Ọyọ lori i aṣa ati irinajo igbafẹ, Hon. Ademola Akeem Ige ati agbẹjọro fun OPC lo tẹwọgba awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn mu ogbontagi Fulani daran daradaran, Isikilu Wakili lọ si ilu Abuja.
Iroyin ti a gbọ ni pe ọkan lara awọn oludamọran fun Aarẹ Muhammadu Buhari lo paṣẹ pe ki wọn gbe awọn eeyan naa wa si ilu Abuja.
Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa wa lara awọn ẹṣọ to ṣiṣẹ pọ mu Wakili lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo.
Amọ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ fun BBC Yoruba pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa si wa ni ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Iyaganku niluu Ibadan.
Ẹsun ifipabanilopọ, ijinigbe ati ipaniyan ni wọn awọn eeyan Ibarapa fi kan Wakili ki ọwọ OPC to tẹ ẹ.
Ẹwẹ, Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams bu ẹnu atẹ lu bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ju awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to wa labẹ rẹ si atimọle.
O ni iranwọ lasan ni awọn OPC ṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa lori ati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ kaakiri ipinlẹ Oyo.
Gani Adams ṣalaye ọdaran pọnbele ni Wakili, o ni o kan n dibọn lasan ni fawọn ọlọpaa.