Yollywood: Lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí, Toyin Abraham fi orin yẹ́ Iyabo Ojo sí níbi ìsìnkú ìyá rẹ̀, Òṣùpá fíi ìkíni ọjọ́ ìbí ránṣẹ́ sí Pasuma

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbo oṣere tiata lọsẹ yi lamilaka pẹlu awọn iṣẹlẹ manigbagbe to waye nibẹ.

Bo ti lẹ jẹ wi pe awọn iṣẹlẹ kan jẹ ohun to ba tijo tayọ wa, awọn miran ko fi tara tara jẹ ohun idunnu.

Ninu oṣẹ taa n wi yi, nibẹ ni awọn kan ti ṣe oku iya wọn tawọn mii ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ti wọn si da awọn mi lọla pẹlu pe wọn fi orukọ wọn sọri opopona.

Ni meni meji, ẹ jẹ ka wo ohun to ṣele lagbo awọn oṣere

Wahala fawọn ti wọn ko fi opopona sọri wọn!

Akọle ree ti Falz the bahd guy kọ soju opo rẹ ni Instagram lati fi han pe wọn ti fi orukọ opopona sọri rẹ.

Falz Falana Lane lorukọ ti wọn sọ oju ọna naa baa tiẹ mọ adugbo ibi ti opopona naa wa.

Falz to jẹ ọmọ gbajugbaja agbẹjọro agba Naijiria, Femi Falana wa lara awọn ọdọkunrin ti o n mi agbo akọrin ati oṣere Naijiria titi.

Yemi Alade ati Dorathy Bachor wa lara awọn to fi ọrọ ikini ranṣẹ si

Iyabo Ojo bẹrẹ isinku Iya rẹ, Toyin Abraham forin yẹ si

Igba ipọnju laa mọ ọrẹ.

Ninu awọn elere tiata Yoruba lobinrin to jẹ wọlewọde ara wọn ni Toyin Abraham ati Iyabo Ojo wa.

Bi igba pe ka ni ''five and six'' lawọn mejeeji yi ti awọn Yoruba a maa pe ni kori kosun.

Lasiko isinku Iya Iyabo Ojo, Toyin Abraham jẹwọ pe ọrẹ tootọ loun pẹlu bi o ti ṣe fi orin iyin dagbere fun iya ọrẹ rẹ.

Ṣaaju asiko yi ni Iyabo Ojo ti kede eto isinku iya rẹ to si n fi orisirisi aworan iya rẹ soju opo Instagram rẹ.

Pasuma ati Osupa-ọjọ pẹ ti a ti n ba ọrẹ bọ

Kunle Afod, Saidi Balogun, Salawa Abeni to fi mọ Sound Sultan wa lara awọn to ki Wasiu Alabi Pasuma ''ọrọbọkibọ Creator'' ku orire ajọdun ọjọ ibi.

Iba Barakah bi awọn eeyan ti ṣe mọ tun fi ọdun kan kun ọjọ lorilẹ eepẹ ni ọjọ Eti tii ṣe ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2020.

Amọ ṣa, eyi to ṣe ni ni ''Awww'' ninu awọn aworan ati ọrọ ikini lọjọ ibi rẹ ni ti ọrẹ rẹ Kingsaheed Osupa to fi aworan yi ati ọrọ soju opo Instagram.

Ninu aworan yi, o ni ọrẹ atijọ da ju eyi ta ṣẹṣẹ ni lọ.

O tun fi adura si pe Iba-Wassy ọlọpẹ yoo ṣe ọpọ ọdun laye.

Pasuma naa da lohun to si ni oun dupẹ ore yi.Koda o pe Osupa ni inagijẹ rẹ ti ọpọ eeyan ko mọ''jacky''