Coronavirus treatments: Lẹ́yìn ìgbélé Coronavirus, ọ̀nà wo ni mo lè gbà láti bọ́ l'ọ́wọ́ níní Covid-19.

Obinrin kan pẹlu ibomu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Irú ewu wo ni eni to dúró tì mí lórí ìlà tí a tò sí láti wọ ọkọ̀ BRT, àbí ṣe mo sì le máa lo si ilé oúnjẹ tàbí ki n máa wọkọ̀ èrò?

Bí àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè ṣe n sẹ́wélé òfin ìgbélé, tí àwọn ènìyàn si ti ń padà sí àwùjọ fún onírúurú ìbáraeníse pọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló tí n fòyà lórí bi wọn ò ṣe ni kó ààrùn Coronavirus, èyí to sì lè mú àjàkálẹ̀ ààrùn ẹlẹ́kejì bẹ́ sílẹ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Erin Bromage to jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn èròjà tó ń gbógun ti ààrùn lágọ̀ọ́ ara bá wa sọ̀rọ̀ lórí awon ọ̀nà tí a lè gbà láti mú àdínkù bá ewu kíkó ààrùn Coronavirus, o jẹ́ olùkọ́ ìmọ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn ni Fásitì Massachusetts Dartmouth ní US, o sì ti bojú tó ààrùn Coronavirus yìí láti ìgbà to ti bẹ̀rẹ̀.

O rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa bi a ṣe lè lanilọ́yẹ̀ nípa ǹkan ti sáyẹ́nsì sọ ju kí a pèé ní onímọ̀ nípa ààrùn kan ni pàtó lọ, o tí kọ àwọn ǹkan to pọ̀ nípa Coronavirus lórí ayélujára ti àwọn ènìyàn to le ni mílíọ̀nù mẹ́rindínlógún sì ti kà á ní àkà tún kà.

Àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ rèé láti wà ní àlàáfíà bí a ṣe ń padà sí bí a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Kí ni ìdí ti èèyàn fi ń ṣàìsàn?

Awọn ero nibi ode olorin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bromage ni ọ̀pọ̀ ló ń lùgbàdì ààrùn Covid-19 nínú ilé wọn nítorí ọ̀kan nínú ẹbí wọn tó ní ló pín fún gbogbo ẹbí lẹ́yìn tó ti rí ààrùn naa he nígboro

Ṣùgbọ́n bi ènìyàn ba kúrò nínú ilé ńkọ́? Șé ewu àti kó ààrùn Coronavirus wà ti mo bá lo ṣe ère ìdárayá níta pẹ̀lú àwọn tí wọn ò lo ìbòmú? Kò dájú gẹ́gẹ́ bi ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣe sọ.

"Ní ìta gbangba àwọn èròjà míràn wa tí kò ni jẹ́ kí ààrùn naa ràn, ènìyàn máa n mi gúle-gúle sínú àti síta lásìkò eré ìdárayá, àsìkò yìí kéré jọjọ fún kòkòrò yii láti bọ́ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bo se sọ fun BBC.

" kí o tó ni ààrùn naa, a jẹ́ pé olúwa rẹ̀ ti koju àwọn kòkòrò tó tó iye èyí tó le fún ènìyàn ni ààrùn náà, pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ nípa MERS àti SARS, ìgbàgbọ́ ni pé o gbọ́dọ̀ tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún kan kòkòrò naa ti yóò wọ àgọ́ ara ki èèyàn to le ni ààrùn naa gẹ́gẹ́ bo se ko sójú òpó ayélujára rẹ̀.

Arabinrin kan n sare ni gbagede kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣàlàyé pé bótilẹ̀ jẹ́ pé àríyànjiyàn wà lórí iye kòkòrò àìfojúrí tí èèyàn ti fa símú ki o tó ni ààrùn naa, síbẹ̀ ó ṣeéṣe kí o gba èyí láàrin èémí kan tàbí mẹ́wàá, èyíkéyìí le mú ènìyàn ni ààrùn náà.

Èyí túmọ̀ sí pé iye àsìkò tí a bá lò pẹ̀lú aláàrùn Covid-19 ni yóò sọ bóyá ènìyàn leè kó ààrùn náà, tí a bá lo àsìkò kúkúrú bí ti àwọn to n sáré lójú pópó, o ṣeéṣe ki a máa ni ààrùn náà kódà bi kò sí àlàfo mítà méjì, nítorí náà, àwọn ti ó yẹ kó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n ni àwọn tó ti fàmìhàn

Ọkunrin ati Obinrin kan n sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lóòótọ́ ni ikọ́ àti kàtá máa ṣe ìtànkálẹ̀ ààrùn, ṣùgbọ́n o ní bi èyí ṣe lè wáyé. Ikọ́ ẹ̀ẹ̀kan lè gbé àwọn kòkòrò ẹgbẹ̀rún mẹ́ta síta tó sì le rìn ìwọ̀ Mítà ọgọ́rin láàrín wákàtí kan gẹ́gẹ́ bí Bromage ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò yìí si ló tóbi to fi je pé ilẹ̀ ni yóò jábọ́ sí, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fúyẹ́ tí won sì le dúró nínú afẹ́fẹ́ tàbí kí wọn fò wọ yàrá.

Tí o bá wa jẹ́ pé inú àkàsọ̀ ìgbàlódé ní ó ká ọ mọ́ tí ẹni náà ba wá sín, ìlọ́po mẹ́wàá ni ìṣòro tìrẹ.

Tí ènìyàn ba wá sín lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo kòkòrò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ni yóò jáde tó sì kéré jọjọ, èyí leè rìn kìlómítà tó lé ní ọ̀ọ́dúrún láàrin wákàtí kan, bí Bromage ṣe sọ.

"Bí eniyan ba wá ni ààrùn náà, àwọn kòkòrò to ń jáde kọjá milionu méjì to sì ni àwọn èròjà ààrùn naa nínú"

"Nítorí náà, tí o bá n ba ènìyàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ tí ẹni náà sì sín tàbí wúkọ́ sí ọ lójú, òó ríi bóse rọrùn láti gba kòkòrò bíi ẹgbẹ̀rún kan tí ẹni náà ba tún wa ní ààrùn náà.

Tí o ò bá tún wá sí níbẹ̀ lásìkò náà, àwọn kòkòrò àìfojúrí yìí le wà nínú afẹ́fẹ́ fún ìṣẹ́jú péréte ti o sì ṣeéṣe kí o tí fa èyí tó tó sì mú lásìkò péréte náà, tí ààrùn yóò sì wọlé dé.

Bí àwọn tí kò fàmì hàn ṣe ń pín

Ọkunrin kan de fila o n kọja loju popo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

A mọ̀ pé lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún ni ààrùn náà tó máa n fàmìhàn tó bá mú ènìyàn, ṣùgbọ́n ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ síní fàmìhàn nkọ́, àwọn míràn kò tilẹ̀ ni fàmìhàn rárá.

Èémí wọ́n lásán máa n tí ààrùn Coronavirus jáde sí àyíká.

Báwo lo ṣe pọ̀ tó?

Èémí ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo le tí láàrin àádọ́ta sí ẹgbẹ̀rún márùn-ún kòkòrò naa síta, ṣùgbọ́n kíá lo sábà máa jábọ́ sílẹ̀

Nítorí naa díẹ̀ nínú kòkòrò yii ni a o ríi tobba jáde láti ara èémí gẹ́gẹ́ bi àlàyé rẹ̀ fún BBC.

Ní ti èémí ko sí eni tó mọ iye kòkòrò Coronavirus yìí to n jáde lẹ́ẹ̀kan náà, Ṣùgbọ́n Bromage sọ pé ìwé ìgbà dé gbà kan sọ pé ẹnikẹ́ni to bá ní ọ̀fìnkìn, ó máa ń ti kòkòrò mẹ́ta sí ogún jáde láàrín ìṣẹ́jú kan.

Bí àlàyé yìí ba wá rí bẹ́ẹ̀, o túmọ̀ sí pé, èèyàn yóò mi èémí naa fún ìṣẹ́jú àádọ́ta láti gba ẹgbẹ̀rún kan kòkòrò náà ti yóò fi ní ààrùn Covid-19 (Atọ́ka ni àlàyé èyí jẹ́).

Aworan kan to n ṣe apẹrẹ awọn ami idamọ arun coronavirus

Nítorí náà a o rí pé ko dájú láti kó ààrùn Coronavirus látàrí pé ènìyàn wà nínú ilé kan náà pẹ̀lú ẹni tó ní ààrùn Coronavirus ṣùgbọ́n tí kò fàmì hàn bí ikọ́ àbí kàtá kò na ṣeé.

Bromage sọ pé Ọ̀rọ̀ sísọ le ṣe àfikún kòkòrò to jáde bíi mẹ́wàá sí igba láàrin ìṣẹ́jú kan, bákan náà ni ariwo pípa tàbí orin kíkọ leè fi kún iye kòkòrò tó ń jáde sínú afẹ́fẹ́.

Àwọn kòkòrò yìí a ma wa láti ibi kọ́lọ́fín ẹ̀dọ̀ fóóró níbi tó jé pé ààrùn náà ti gbilẹ̀ sí nítorí agbára lo fi n jáde nítorí ariwo tí ẹni náà ń pa.

"Fún ìdí èyí gbogbo ǹkan tó bá mú ààrùn Coronavirus jáde sínú afẹ́fẹ́ láti inú ẹ̀dọ̀ fóóró yóò pọ̀ gidigidi, bótilẹ̀ jẹ́ pé kíkó ààrùn yìí nínú afẹ́fẹ́ kò tíì fìdí múlẹ̀ dáadáa síbẹ̀ ìtànkálẹ̀ ààrùn yàtọ̀ sí láti inú ilé máa n wáyé latari àwọn ti kò fàmì hàn.

Àyíká wo ló léwu jù?

Awọn ọkunrin mejeeji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Láì dénà pẹnu àwọn tó n tọ́jú àwọn alárùn yìí ló léwu fún jù.

Ṣùgbọ́n àwọn àyíká miran náà tún burú jai, bí àpẹẹrẹ àwọn tó wa nínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn tí wọ́n wà nínú ọ́fíìsì kan naa, àwọn ti wọ́n péjọ síbi ìnáwó ìyàwó, ọjọ́ ìbí, ìgbáradì akọrin tàbí ìsìnkú, èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí iye àsìkò ti wọ́n lò pẹ̀lú alárùn náà ni.

"kódà ki wọ́n fi àlà mítà àádọ́ta jìnà sírawọn, ìsun téré tó n kan ẹnìkọ̀ọ̀kan tó láti jẹ́ kí wọ́n ni ààrùn naa, nítorí naa bi a ṣe n padà sẹ́nu iṣẹ́ àwọn ilé iṣẹ́ kan yóò ní láti ṣe àtúnṣe

Àwọn ọ́fíìsì ti kò ní ibi tí atẹ́gùn le gbà wọlé léwu gidigidi, Bromage ṣàpèjúwe pé ìdá mẹ́rìnleláàọ́run ninu òjìlénígba o dín mẹ́rin ọ́fíìsì ló ni ààrùn Coronavirus ni orílè èdè South Korea, ọ̀pọ̀ sì jẹ́ àwọn to wà nínú ọ́fíìsì kàn náà tó tẹ́ gbayawu ṣùgbọ́n tí àtẹ̀gùn rẹ̀ kò to ǹkan.

Aworan eeyan kan lori ibusun alaisan ni ileewosan kan

Àwọn Dókítà eyín náà wà nínú ewu yìí nítorí irú isẹ́ wọn.

Ó ní àwọn olùkọ́ náà yóò wà nínú ewu, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n to ti darúgbó ló pọ̀jù tí wọ́n si ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kún kíláàsì fọ́fọ́, ìrònú jinlẹ̀ gbọ́dọ̀ wà kí irú àwọn yìí tó padà sẹ́nu isẹ́ fún ìgbé ayé àlàáfíà

Nínú ilé tàbí níta

Bromage ní àwọn to kó ààrùn Coronavirus ní ta ko fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn to kóra jọ pò sí inú ibì kan tí won ti ń kọrin, pariwo ló wọ́pọ̀, tí ènìyàn bá ju kòkòrò náà sì àárín ita, afẹ́fẹ́, oòrùn òtútù leè mú àdínkù bá ìtànkálẹ̀ rẹ̀, ẹ̀wẹ̀, ìjìnà sira ẹni àti mímú àdínkù bá ìbáṣpọ̀ elérò yóò rán gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ láti fòpin sí ààrùn Coronavirus.

Bákan náà ni àwọn ibi tó jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí atẹ́gùn, ti àwọn ènìyàn si maa n gba èémí fúnra ẹni ni, yóò nira díẹ̀ láti máà ni ààrùn náà, àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé kò fi bẹ́ẹ̀ léwu, nítorí pé àsìkò péréte ni wọn lò ní àyíká kan.

Ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ewu to wá níbi tí a n lọ.

Aworan aya nipa dokita kan

Bí a bá fẹ́ lọ sóde, a ní láti ṣe àgbéyẹ̀wò irú afẹ́fẹ́ tí ènìyàn yóò máa gbà sì mú níbẹ̀, iye ènìyàn tó ṣeéṣe kí o bá pàdé níbẹ̀ àti iye àsìkò tí óò lò.

To ba jẹ́ ọ́fíìsì gbayawu ni o ti n siṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn péréte, ewu bíntín ni ṣùgbọ́n ti èrò ba pọ̀ nibẹ̀, o ní láti gbé e yẹ̀wò dáadáa.

Tó bá jẹ́ pé isẹ́ tìrẹ gba kí o maa bâ àwọn oníbàrá rẹ sọ̀rọ̀ lójú kojú ni tàbí èyí tó n mú ariwo dání, o léwu fún ọ

Tó bá jẹ́ pe kí o lọ rajà lásán láwọn ilé ìtajà ni, níwọ̀ba àsìkò tí o n lò níbẹ̀, ewu rẹ̀ kéré jọjọ, ṣùgbọ́n fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtajà náà Ó ṣe pàtàkì ki a maa rántí pe kìí ṣe ṣínsín síni nìkan ni o yẹ ki a máa ṣọ́ra fún, e rántí pé àwọn kòkòrò yìí maa n bàlé àwọn irinsẹ́ tí à ń lò nítorí naa, o se pàtàkì láti máa fọ owọ́ rẹ déédéé kí o si ṣọ́ra láti máa fi owọ́ kan ojú.

Bákan náà, e ṣọ́ra fún fífẹ́ àtẹ̀gùn láti paná àbẹ́là lórí àkàrà oyinbo (cakes) ọjọ́ ìbí.

Aworan iroyin nipa coronavirus
Aworan iroyin nipa coronavirus