Coronavirus in Nigeria: Mohammed, ọmọ Abubakar Atiku sọ̀rọ̀ lórí àrùn Coronavirus tó ń báa finra

Oríṣun àwòrán, Mohammed Atiku Abubakar
E ye gbe iroyin ofege kaakiri papaa julọ lasiko ajakalẹ aarun coronavirus yii.
Mohammed Atiku, ọmọkunrin oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar lo ṣe ikilọ yii lati ibi to ti n gba itọju niluu Abuja, lẹyin to lugbadi aarun covid-19.
Mohammed ni iroyin ofege le ṣakoba nla fun ilera awọn eeyan papaa julọ awọn ti aarun covid-19 n ba finra lọwọ.
Ọmọ Atiku ni o jẹ iyalenu fun oun pe awọn alabaagbe oun n gbe ayederu iroyin kiri nipa oun lẹyin ti oun lugbadi aarun covid-19.

- Ó ṣe é ṣe kí o ti ní coronavirus kí ó má mọ̀ nítorí pé ó kò rí àpẹẹrẹ
- Ẹ wo bí ẹ ṣe lè ṣe "hand sanitizer" nínú ilé yín láàrín ìṣẹ́jú díẹ̀
- Ǹjẹ́ fífi omi àti iyọ̀ yọnu leè dènà àrùn Coronavirus?
- Ìgboro ilú London dá páro nìtorí àrùn Coronavirus
- Lásìkò kónílé-ó-gbélé coronavirus yìí, Òbí gbọ́dọ̀ fi àsìkò sílẹ̀ fi tọ́jú àwọn ọmọ wọn
- Ó ṣe é ṣe kí o ti ní coronavirus kí ó má mọ̀ nítorí pé ó kò rí àpẹẹrẹ
- Lásìkò kónílé-ó-gbélé coronavirus yìí, Òbí gbọ́dọ̀ fi àsìkò sílẹ̀ fi tọ́jú àwọn ọmọ wọn

O ni iroyin ofege ko ni ipa kankan lara oun nitori agboole oloṣelu loun ti wa, ṣugbọn akoba nla ni ayederu iroyin n ṣe fun ilera awọn to n ṣaisan lọwọ lasiko yii.
"Ẹ jẹki a gbe oṣelu ti sẹgbẹ kan lasiko yii, ki a pawọpọ, ki a si fimọ ṣọ̀kan, eyi ni a fi le bori ajakalẹ aarun coronavirus yii," ọmọ Atiku lo sọ bẹẹ.
Mohammed ni ibẹru-bojo mu oun nigba ti wọn kọkọ gbe oun de ile iwosan, nitori oun ni ẹni akọkọ ti yoo kọkọ ni aarun covid-19 l'Abuja.
O ni oun ni gbagbọ pe laipẹ laijina, oun yoo kuro nile iwosan ti oun yoo si jajabọ lọwọ coronavirus patapata.
Ọmọ Atiku gboriyin fawọn oṣiṣẹ eleto ilera fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe papaajulọ lasiko yii.
Coronavirus in Nigeria: Akọrin ẹ̀mí, Tope Alabi gbé N200, 000 kalẹ̀ fáwọn aláìní lásìkò Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Tope alabi
Gbajugbaja akọrin ẹmi, Tọpẹ Alabi ti ke sawọn olorin ẹmi lati da si eto igbayegbadun fawọn to ku diẹ kaato fun lasiko igbele ti ijọba lẹka gbogbo n kede lati dena itankalẹ arun COVID-19
Tọpẹ Alabi to fi sita lori ikanni abanidọrẹ, Facebook rẹ ṣalaye pe lootọ igboro le diẹ, sibẹ bi o ti wu ko kere awọn olori ẹmi atawọn to ba nifọn leekanna naa lee ṣe iranwọ fun araalu.
Akọrin ẹmi miran, Tim Godfrey lo gbe eto naa kalẹ leyi ti wọn fẹ fi ko ọgbọn miliọnu naira jọ fun riran awọn ti ko lee ra ounjẹ lasiko igbele yii lọwọ.
Tọpẹ alabi ni ko yẹ ki awọn olorin ẹmi duro de ijọba lasiko yii ki wọn to ran awọn ti ko ni lọwọ. O fi kun un pe niwọnba ohun ti ẹnikọọkan ba ni lo lee fi ran awọn eeyan yii lọwọ.
Iroyin ti alakoso eto naa fi sita ṣalaye pe ẹgbẹrun lọna igba naira ni Tọpẹ Alabi fi silẹ fun aṣuwọn naa.













