You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mike Ifabunmi, àwọn òṣèré Yorùbá kí BBC Yorùbá kú ayẹyẹ
Ọpọlọpọ awọn eeyan jankan jankan lo ti n fi ikini ku ayẹyẹ ọdun meji ranṣẹ si ileeṣẹ BBC Yoruba tẹ o si maa ri gbogbo rẹ loju opo wa bi oni ba ṣe n lọ.
Ka to wi ka to fọ ka to ṣẹju pẹrẹ, ọdun meji ti pe. Ọmọ kekere ana ti wa wa dagba.
Akanṣe eto pataki ti a ṣe fun ayẹyẹ ọdun meji BBC Yoruba loju opo Facebook wa niyii nisalẹ.
Awọn iroyin pataki taa ti mu wa fun un yin ko lonka lati igba ti BBC Yoruba ti bẹrẹ.
Kẹrẹkẹrẹ nigba ti igbohunsafẹfẹ ileeṣẹ BBC Yoruba ati kiko iroyin sori ẹrọ ayelujara bẹrẹ lọjọ naa lọhun, wẹrẹ wẹrẹ la n wọle si ọkan awọn eeyan.
Eyi ko tii dawọ duro bayii o koda, iroyin wẹrẹwẹrẹ ti di eyi ti wọn n rọ lu witiwiti lati ka bayii to bẹẹ ti okiki BBC Yoruba ti kan tayọ orilẹede Naijiria to si ti de gbgobo agbaye.
Iroyin lori eto oṣelu atawọn eekan Naijiria
BBC Yoruba taa ṣe ifilọlẹ rẹ ni dede ọjọ oni lọdun meji sẹyin, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji ọdun 2018 ni ifilọlẹ pataki nla naa waye ni ipinlẹ Eko, Naijiria.
- Yàtọ̀ sí eku gọ́tà tàbí èku inú ilé, kò sí eku téèyàn ò lè jẹ - Òǹtajà Eléwé ọmọ
- Àwọn ọba tó wà lábẹ́ mi ń talẹ̀ nítàkutà- Oluwo
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ti bẹ̀rẹ̀ òfin tí yóò máa mú àwọn olùkọ́ fásitì tó ń bèrè fún ìbálòpọ̀
- Ibà Lassa wọ ìpínlẹ̀ Èkó!
- Ó dá mi lójú pé ìwá ìbàjẹ́ ló fa àrùn Coronavirus - Ọ̀gá àgbá EFCC
Itan ati Aṣa Yoruba
Eto Idibo Naijiria
Ọrọ to kan araalu
Lara awọn iroyin manigbagbẹ ti a ti sẹ ni yii nipa eto idibo gbogboogbo to waye lorilẹede Naijiria ni ọdun 2019, eto oṣelu ni Naijiria, asa, iroyin kayeefi to fi mọ iroyin awọn oṣere tiata Yoruba lorilẹede Naijiria.